Adigunjale pade iku ojiji nibi to ti n ji ọkada gbe sa lọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ogbologboo adigunjale kan pade iku ojiji nibi to ti n gbiyanju lati ji ọkada ọlọkada gbe sa lọ niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Ọkunrin adigunjale ọhun ti ko sẹni to ti i mọ ibi to ti wa ni wọn lo da ọlọkada kan lọna lagbegbe ileetura Sunview, to wa ni Alagbaka, to si fipa ja ọkada rẹ gba, to n sa lọ.

Ariwo ti ẹni to ja lole n pa lawọn ọlọkada ẹgbẹ rẹ gbọ ti wọn fi bẹrẹ si i le ogboju ọlọsa ọhun kaakiri agbegbe naa.

Ibi to ti n wa gbogbo ọna ti yoo fi raaye sa mọ awọn to n le e lọwọ lo ti subu lori ọkada to n gun, to si ku loju ẹsẹ.

Awọn eeyan agbegbe naa ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti, ilẹ si ti su daadaa ki wọn too gbe igbesẹ ati gbe oku rẹ kuro lẹgbẹẹ titi ibi to ku si.

Leave a Reply