Olusẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Ọkan ninu awọn oludije ibo abẹle ẹgbẹ APC to waye lọsẹ to kọja, Dokita Nathaniel Adojutẹlẹgan, ti fi ẹhonu han lori bi wọn ṣe kede orukọ Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.
Oludije ọhun to ni ẹyọ ibo marun-un pere la gbọ pe o ti fi iwe ẹhonu rẹ sọwọ si Chris Baywood Ibe to jẹ alaga igbimọ to fẹẹ gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idido abẹle naa.
Adojutẹlẹgan ni esi didbo ọhun ko gbọdọ jẹ itẹwọgba nitori pe ọna ti wọn fi ṣeto rẹ lodi patapata si ofin ẹgbẹ APC ati ilana ti ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii fi lelẹ lori siṣeto iru idibo bẹẹ.
O ku bii ọjọ meji pere ki idibo naa waye lawọn oludije mọkanla ti kọkọ fẹhonu han lori ilana ti wọn fẹẹ lo.
Gbogbo wọn ni wọn fimọ sọkan, ti wọn si jọ kọwe si awọn asaaju ẹgbẹ wọn l’Abuja pe ọna ti wọn fẹẹ fi seto ibo ọhun ko tẹ awọn lọrun rárá.
Yaya Bello to jẹ alaga igbimọ idibo abẹle naa lo fun wọn lesi loju ẹsẹ pe ki i ṣe awọn oludije ni yoo maa fọwọ lalẹ fun awọn aṣaaju ẹgbẹ lori ilana to yẹ ki wọn lo.