Adura ati ifọwọsowọpọ wa pẹlu ọga ṣọja ni Naijiria fi le bọ ninu wahala eto aabo – Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo tilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ke si gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati gbaruku ti ọga awọn ṣọja ti wọn ṣẹṣẹ yan lorileede yii, Major Gen. Faruk Yahaya, ko le baa ṣaṣeyọri si rere.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin kabiesi, Alli Ibraheem, fi sita ni Oluwo ti ni wahala to n fojoojumọ yọju lẹka eto aabo ilẹ wa yii ti pe fun ki tolori-tẹlẹmu tọ soju kan naa, ko baa le ho.

O ni ọna kan ṣoṣo ti Yahaya fi le ṣaṣeyọri, ti wahala yii yoo si di afisẹyin teegun n fiṣọ ni ki gbogbo ọmọ orileede Naijiria ba a fọwọ sowọ pọ lati wa ojutuu si wahala yii.

Ọba Adewale fi kun ọrọ rẹ pe bi ọrọ aabo ṣe mẹhẹ bayii ko dun mọ oun ninu rara, ṣugbọn oun mọ pe akinkanju to ni imọ kikun ninuu bi a ṣe n gbogun ti iwa igbesunmọmi ni ọga awọn ṣọja tuntun naa.

O ni ti awọn araalu ba ti le wa niṣọkan pẹlu ileeṣẹ ologun, yoo jẹ koriya fun awọn ṣọja, wọn yoo si ṣiṣẹ naa pẹlu idaniloju pe gbogbo ọmọ Naijiria lo wa lẹyin awọn.

Kabiesi sọ siwaju pe awọn ọmọ orileede yii gbọdọ da igbẹkẹle ti wọn ni ninu ileeṣẹ ologun pada, ki wọn si sọ ifẹ wọn fun ileeṣẹ naa di ọtun.

O ni oun nigbẹkẹle kikun ninu ipa Yahaya pe yoo ṣe takuntakun lati ri i pe awọn araalu le sun lai foya rara, o si pe fun ki gbogbo eeyan maa fi adura ran an lọwọ lati le jajaṣẹgun lori awọn ikọ agbesunmọmi ti wọn wa kaakiri.

Oluwoo ni “Ẹ jẹ ka fọwọ sowọ pọ lati le awọn janduku ti wọn n da orileede wa ru jade. Gbogbo wa la ni orileede yii, a ni ipa lati ko lati tu aṣiri awọn to n yọ wa lẹnu.”

Leave a Reply