Afaimọ ki Damilọla ma ṣẹwọn o, tẹtẹ lo ta lawin ti ko rowo san n’Ileefẹ

Florence Babaṣọla

Ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun, Damilọla Daramọla, ti foju ba ile-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii, lori ẹsun pe ko rowo tẹtẹ to ta san.

ASP Sunday Ọsanyintuyi to jẹ agbefọba ṣalaye fun kootu pe lọdọ ọmọbinrin kan, Akindele Mercy, ni Damilọla ti ta tẹtẹ Bet Naija ẹgbẹrun mẹtala o din ọọdunrun-un naira (#12,700) lọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun yii, lagbegbe Ọlọnade, niluu Ileefẹ.

O ṣalaye pe iwa to hu ọhun jẹ eyi to le da omi alaafia agbegbe naa ru, to si nijiya labẹ abala ọtalelugba o din mọkanla (249) ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Agbejọro olujẹjọ, Unah Sunday, bẹbẹ fun beeli rẹ lọna irọrun lẹyin to sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ A. A. Adebayọ fun un ni beeli pẹlu ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn naira (#25,000) ati oniduuro kan niye kan naa.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply