Faith Adebọla, Eko
Bunmi Ọladuntoye, afẹsọna awakọ ofurufu awọn ologun, Taiwo Aṣaniyi, to doloogbe lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ninu ijamba baaluu to ṣẹlẹ niluu Kaduna, sọrọ nipa iku olulufẹ ẹ.
Ba a ṣe gbọ, inu oṣu kẹta to kọja yii lawọn tọkọ-taya lọla naa ṣe ayẹyẹ mọ-mi-n-mọ-ọ (introduction) wọn, ti wọn si n foju sọna lati ṣeyawo alarinrin ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii. Ṣugbọn iku ojiji yii ti sọ gbogbo ipalẹmọ ọhun dofo.
Ninu ọrọ aro kan ni ololufẹ Taiwo ti fi imọlara rẹ han nipa oloogbe yii, o ni inu oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, loun gba fun un pe awọn maa di tọkọ-tiyawo laipẹ, o si sọ bi afẹsọna oun yii ṣe jẹ eeyan atata to.
Eyi lawọn ọrọ aro ti Bunmi Ọladuntoye, afẹsọna oloogbe naa, kọ nipa ololufẹ ẹ:
Fẹmi, mi o kabaamọ pe mo ba ẹ rinrinajo yii, o bi mi leere ninu oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, pe ṣe ma a fẹ ọ, mo si fesi pẹlu idunnu pe “bẹẹ ni.” Lara ọrọ to o ba mi sọ kẹyin ni pe ki n maa ṣe jẹẹjẹ, ki n si lawọ sawọn eeyan. Mo mọ pe ẹlẹyinju aanu ni ọ, bẹẹ ni, o lawọ gan-an ni, Fẹmi mi….
Fẹmi mi, Olowo ori mi, ta lo maa jisoro irun mi bayii ti mo ba ṣẹṣẹ ṣe e tan, ta lo maa rẹrin-in si mi to maa pe mi ni fain gẹl, to maa sọ fun mi pe emi ni mo rẹwa ju lọ laye. Mo ti sunkun titi agara da mi. Awọn eeyan bẹ mi, wọn ba mi sọrọ, James ati Kamal sọ fun mi pe ko wu ọ ki n wa nipo ibanujẹ bii eyi. Mo si gba bẹẹ, tori nigbakuugba ti inu mi o ba dun ti mo ba n sunkun, kia lo ti maa n gba mi mọra, to o maa sọ fun mi pe, ‘ewo tun ni gbogbo eyi?’ O yẹ ki gbogbo aye mọ bo o ṣe jẹ eeyan atata to. Ẹyin ọmọ Naijiria, gbogbo agbaye, ọkọ mi Flight Lieutenant Taiwo Aṣaniyi, jẹ eeyan nla to fi gbogbo aye ẹ sin orileede ẹ. Ẹ ba mi ṣadura fun un, ẹ gbadura fawọn mọlẹbi ẹ, ẹ ṣadura fun mi. Adigun mi, Fẹmi mi, adun ṣokoleeti aye mi, sun un re o.
Mo maa ṣikẹ iranti ẹ, tori ọpọ nnkan didun didun la ti jọ ṣajọpin ẹ. Lai ti i ṣegbeyawo, niṣe lo n kẹ mi loju nimu, to o n gbe mi gẹgẹ bii iyawo ọṣingin. O maa n sọ fun mi pe ‘Ifẹ mi, ma wọri, gbogbo ẹ maa daa.’
Adun aye mi, jọọ ma fi mi silẹ o, Olufẹmi Taiwo Aṣaniyi, mo nifẹẹ ẹ titi lae.