Afẹsọna Oluwọle lo n f’ọkada gbe lọ tawọn Fulani fi yinbọn pa a n’Igboọra

Faith Adebọla

Awọn Fulani agbebọnrin ti wọn n ṣoro bii agbọn lagbegbe Ibarapa si Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, tun ṣiṣẹ laabi wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Oluwọle Oke, ẹni ọgbọn ọdun, kan ni wọn da duro lori ọkada rẹ, wọn yinbọn pa a danu, lai ṣẹ lairo.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, adugbo Iṣẹrin, niluu Igbora, nijọba ibilẹ Aarin-Gbungbun Ibarapa, ni ọkunrin naa n gbe, oun ni kọmandaati ẹgbẹ ‘yan bii ologun’ kan ti wọn n pe ni Man-O-War lagbegbe ọhun.

Wọn ni afẹsọna ọkunrin ọhun to waa ki i lo ni koun gbe pada si ilu rẹ ni Iwere-Ile, ni wọn ba jọ gun ọkada Bajaj rẹ, wọn lọjọ ti n tẹnu bọ’po lọ lọjọ ọhun.

Nigba ti wọn fi maa de aarin Iganna si Iwere-Ile lori titi marosẹ ti wọn n tọ bọ, wọn ri i tawọn Fulani naa tan ina tọọṣi ọwọ wọn si i pe ko duro, ṣugbọn nitori okunkun to ti ṣu, ọkunrin naa ro pe awọn ọlọpaa ni wọn n da oun duro ni, ko mọ pe awọn Fulani ni.

Wọn ni bo ṣe duro lawọn Fulani naa ti sare sun mọ ọn, bi wọn si ṣe ri i pẹlu aṣọ idanimọ (yunifọọmu) awọn Man-O-War to wọ, boya wọn ro pe ẹṣọ Amọtẹkun tabi ọmọ OPC kan ni, gẹgẹ bi afẹsọna naa ṣe sọ, o ni niṣe ni wọn ta a nibọn loju-ẹsẹ, wọn si yipada, wọn wọgbo lọ.

Afẹsọna naa ni jinnijinni ti mu oun, tori oun ti ro pe wọn maa pa oun naa, ṣugbọn wọn ko fọwọ kan an rara, wọn ko si gba foonu tabi ọkada oloogbe naa.

Ẹsẹ lọmọbinrin naa fi rin kuro nibi iṣẹlẹ ọhun ko too pade alaaanu kan to gbe e dele, lo ba fi iṣẹlẹ naa to awọn eeyan leti.

Wọn lawọn to lọ sibi iṣẹlẹ naa ti fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, wọn si gbe oku Oluwọle lọ si teṣan ọlọpaa ni Iganna.

Wọn lawọn ọlọpaa ti yọnda oku naa fawọn mọlẹbi ki wọn le si in lọjọ keji, wọn si lawọn yoo ṣewadi lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply