Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti sọ pe afojusun oun ni lati di aarẹ orilẹ-ede yii tabi alufaa, eyi to ba si kọkọ wa si imuṣẹ loun yoo di mu.
Fayoṣe sọrọ yii lasiko to n ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ latari ọjọọbi ọgọta ọdun to pe laye.
Gomina ana naa ni ero eeyan yatọ si ti Ọlọrun, idi niyi ti erongba oun fi yatọ, oun si dupẹ nitori oun ri aanu gba nile aye, eyi to fẹẹ jẹ koun wa ọna lati sin Ọlọrun si i.
Fayoṣe to ni oun ti fori ji awọn to ṣẹ oun lasiko toun wa nipo gomina ati nigba toun ko si nipo ṣalaye pe awọn kan wa toun ran lọwọ lati goke agba, ṣugbọn wọn ti fi oun silẹ bayii lati dara pọ mọ awọn ọta oun lẹyin ti wọn ri i pe oun ko si nipo mọ.
O sọ siwaju pe ko si ootọ ninu iroyin tawọn kan n gbe kiri pe oun fẹẹ ṣe sẹnetọ, o ni ki i ṣe ipo to dun mọ oun ninu lati di mu rara nitori oun ko le maa ṣe ofin tawọn alaṣẹ ilẹ yii ko ni i ṣamulo.
Nipa ipo aarẹ ilẹ yii to sọ, oloṣelu naa ni bi awọn eeyan bii Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati Ọmọwe Goodluck Jonathan ba le di ipo naa mu, oun naa le ṣe e daadaa. Iwa rere to ni oun hu lati ran ọpọlọpọ eeyan lọwọ lo ni yoo fun oun lokiki lati de ipo naa.
Lori asiko to ba a ninu jẹ ju laye, ọdun 2006 ti wọn yọ ọ nipo gomina lo pe e, bẹe lo ni ọdun 2014 toun tun pada di gomina ni inu oun dun ju.