Monisọla Saka
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Onidaajọ Ibironkẹ Harrison, ti ile-ẹjọ giga ilu Eko, to wa ni Tafawa Balewa Square, nipinlẹ Eko, tun jokoo lori ẹjọ ọga ọlọpaa nni, ASP Drambi Vandi, ti wọn fẹsun iṣekupani kan. Oun ni wọn lo pa obinrin lọọya kan, Arabinrin Bọlanle Raheem, to filu Eko ṣebugbe, lọjọ ọdun Keresi to kọja, iyẹn ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022.
Ninu alaye ọga ọlọpaa yii lo ti sọ fun kootu pe ọta ibọn ti wọn mu wa siwaju ile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹri pe wọn yọ lara obinrin ọhun ki i ṣe latinu ibọn nla alagbeekọrun toun, ati pe latọjọ toun ti daye, toun si ti gba iṣẹ ọlọpaa yii, oun ko ti i riru ọta bẹẹ ri, afigba ti wọn mu un kalẹ ni kootu.
O ṣalaye siwaju si i pe ojo ti n pa igun oun bọ nidii iṣẹ ọlọpaa, ilẹ ti ta, ati pe oun ki i ṣe ọgbẹri lẹnu iṣẹ naa. O ni oriṣiiriṣii idanilẹkọọ loorekoore loun ti gba, ati gbogbo ẹni to ba gba ileewe awọn ọga ọlọpaa kọja lori bi wọn ṣe n lo ibọn atawọn nnkan ija ogun mi-in.
O ni awọn ileewe ẹkọṣẹ ọlọpaa ti ibilẹ toun lọ loun ti mọ nipa oriṣiiriṣii ibọn alagbeekọrun (rifle), ibọn punpu (pistol), atawọn ọta ibọn fawọn agbofinro. Bakan naa lo ni wọn kọ ohun nipa bi wọn ṣe n to ọta ati bi wọn ṣe n yọ ọ kuro, ti wọn yoo da a kalẹ ninu ibọn.
Vandi ni gbogbo awọn ọlọpaa to wa ninu baraaki ni wọn maa n ṣeto ikọni oloṣu marun-un marun-un fun lati tubọ mu ki wọn mọ nipa bi wọn ṣe n lo ibọn si i. Lati le fidi alaye ẹ mulẹ pe o mọ nnkan to n sọ, lo tun fi ṣalaye bi ọta ṣe n ṣiṣẹ ninu ibọn alayinyipo, AK-47 fun wọn.
Nigba to n ṣalaye bi ọrọ naa ṣe waye lọjọ naa, o ni, “Ẹnu iṣẹ ni mo wa labẹ biriiji Ajah, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to kọja, ibọn alagbeekọrun, ti ọta mẹẹẹdọgbọn wa ninu ẹ lo wa pẹlu mi. Ọdọ ẹni ti awọn nnkan ija maa n wa lọdọ ẹ ni mo ti gba a, mo si fọwọ si iwe nibẹ pẹlu.
Aarọ ni mo debi iṣẹ, ṣugbọn mi o le ranti iye aago to jẹ. Emi pẹlu Insipekitọ Ameh ati Ibimene la jọ wa. Ki i si i ṣe emi nikan ni mo gbe ibọn lọwọ, o wa lọwọ Ibimene naa. Ibi ti mo duro si gan-an le ni iwọn ọgọrun-un mita si ibi ti mọto wọn wa. Emi pẹlu awakọ wọn, ati oloogbe la jọ dele iwosan naa. Ki i ṣe inu ọkọ kan naa ni gbogbo wa wa. Titilayọ to jẹ aburo oloogbe ko si ninu mọto pẹlu wa. Aṣọ ọrun mi ko pe gẹgẹ bii agbofinro, nitori aṣọ ile ni mo wọ de ile iwosan Budo, nibi ti wọn ti fi panpẹ ofin gbe mi, ti wọn si ti wọ mi lọ si teṣan ọlọpaa ti mo ti kọ ọrọ akọsilẹ nnkan ti mo mọ nipa ẹ.
“Gbogbo wa lawọn ọlọpaa da duro, ta a si jọ ṣe akọsilẹ ni teṣan Ajah ati ti Panti, wọn o si tu ẹnikẹni silẹ titi ti wọn fi taari wa lọ si Panti. Ọsibitu Budo la wa ti ọga ọlọpaa agbegbe ibẹ ti gba gbogbo ibọn, aṣọ ati nnkan ija to wa lara mi. Ohun ti mo mọ ni pe ọta ibọn mẹẹẹdọgbọn ni mo fọwọ siwee fun. Iru ọta ti wọn gba lara mi yii naa wa ninu magasinni ti wọn gbe kalẹ siwaju ile-ẹjọ, bẹẹ ni wọn o ka gbogbo ọta yẹn loju mi lasiko ti wọn gba a lọwọ mi nile iwosan ọhun.
O ṣe mi laaanu, o si wu mi ki oloogbe ṣi wa laye lonii, nitori mo kabaamọ iku to pa a. Ki Ọlọrun fun ẹmi rẹ ni isinmi”.
Lẹyin to gbọ atotonu ọkunrin naa tan, ni Onidaajọ Harrison sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun yii.