Agba ofifo lasan lawọn gomina to ṣofin pe ki wọn yee fi maaluu jẹko ni gbangba-Akowe Miyetti Allah

Faith Adebọla

Boya lawọn gomina ipinlẹ mẹtadinlogun ti wọn fori kori nipade apero nla kan ti wọn ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, lori ọrọ aabo to mẹhẹ lorileede yii ti i dide nipade ọhun tawọn eeyan nla nla lapa Oke-Ọya fi bẹrẹ si i lodi si ipade naa atawọn ipinnu ti wọn ṣe nibẹ.

Lati ọjọ Iṣẹgun naa lọkan-o-jọkan ọrọ atako ati ibẹnu-atẹ-lu ti n rọjo lati ilẹ Hausa, paapaa lori ipinnu pataki kan tawọn gomina naa ṣe, nibi ti wọn ti ni awọn fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba jake-jado ipinlẹ mẹtadinlogun Guusu orileede yii.

Yatọ si fifi maaluu jẹko tawọn gomina naa fofin de, wọn tun gba Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari, lamọran lati ba awọn ọmọ orileede yii sọrọ lori iṣoro aabo to n fẹju yii, ki Aarẹ si ṣeto ipade apero nla kan ti tolori tẹlẹmu lati origun mẹrẹẹrin Naijiria yoo ti jiroro atunto ofin ilẹ wa, ki wọn ṣeto agbekalẹ ọlọpaa ipinlẹ ati ibilẹ pẹlu ofin to yẹ.

Gbogbo eyi lo wa lara koko mejila ọtọọtọ ti Gomina Rotimi Akeredolu tipinlẹ Ondo ka jade lopin ipade naa pe awọn fẹnu ko le lori.

Ọjọgbọn Usman Yusuf to ti figba kan jẹ Akọwe agba ileeṣẹ abanigbofo ilera tijọba apapọ (National Health Insurance Scheme, NHIS) sọ nipa ipinnu awọn gomina naa, o ni ko bojumu bi wọn ṣe ṣeru ipinnu pataki bẹẹ lai ke si awọn olori Fulani darandaran tọrọ naa kan gbọngbọn. O lọrọ ọhun ko yatọ si keeyan maa fa ori olori lẹyin olori.

Lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan AIT kan lo ti fesi pe “bawọn gomina yii ba fẹẹ fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba loootọ, wọn gbọdọ pese papa ijẹko mi-in fawọn maaluu wọnyẹn ki wọn too ṣeru ofin bẹẹ, ki wọn kan kora wọn jọ si otẹẹli kan, ki wọn lawọn n ṣofin ṣakala bẹẹ ki i ṣe iwa ọmọluabi rara.”

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ onimaaluu Oke-Ọya, iyẹn ẹgbẹ Miyetti Allah Kautal Hore, Ọgbẹni Alhassan Saleh, sọ ni tiẹ pe agba ofifo lasan ni awọn gomina wọnyẹn pẹlu ofin ti wọn ṣe, ata akara ti o ran ikọ si lofin ọhun pẹlu. “Mi o ro pe ohun tawọn gomina yii n sọ ye awọn funra wọn, o si jọ pe wọn fẹẹ ṣojooro kan ni, ṣe awọn darandaran niṣoro orileede yii ni? Ṣe awọn darandaran lawọn ọmọ ẹgbẹ IPOB to n paayan, ti wọn n dana sun teṣan ọlọpaa kaakiri ni?”

Agba oloṣelu ilẹ Hausa kan to tun jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ Arewa Consultative Forum, Alaaji Tanko Yakasai, sọ pe ofin yii o de ijọba apapọ, “ko sẹni to le fipa ni kawọn eeyan tẹle ofin tawọn ṣe lori awọn mi-in”.

Bo tilẹ jẹ pe Yakasai sọ pe oun fara mọ bawọn gomina naa ṣe pe fun bibojuto iṣoro aabo lọna akọtun, o ni ipe ti wọn pe fun atunto ko ṣoju ṣaara. “O ku diẹ kaato fun awọn gomina lati sọ pe atunto gbọdọ waye lai sọ pato ohun ti wọn fẹẹ tun to ati bi wọn ṣe fẹ ko waye. Niṣe ni ki wọn la a mọlẹ ko ye wa ohun ti wọn ni lọkan pẹlu atunto ti wọn n sọ yii. Ni temi o, ohun ti gbogbo eeyan fẹ ti wa ninu iwe ofin torileede yii n lo lọwọ.”

Olori ọmọ ẹgbẹ to po ju lọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa nigba kan, Sẹnetọ Mohammed Ali Ndume, sọ pe niṣe lawọn gomina naa fẹtẹ silẹ ti wọn n pa lapalapa nigba to jẹ ofin ‘ma fẹran jẹko ni gbangba’ ni wọn rannu mọ dipo iṣoro eto aabo ti wọn lawọn tori ẹ jokoo. Ẹni ti wọn maa naka abuku si ni wọn n wa kiri.

Ndume ni “ni temi o, wiwa ẹni ti wọn maa dẹbi ọrọ ru yii ko le yanju nnkan kan. Awọn gomina ni olori ẹṣọ alaabo ipinlẹ ọkọọkan wọn, tori naa, ki lo de ti wọn sọ ohun ti Aarẹ gbọdọ ṣe lai ran ti ara wọn. Wọn ti fi koko ọrọ silẹ to yẹ ki wọn sọ silẹ.”

O tẹsiwaju pe ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe ọrọ fifi maaluu jẹkọ ni gbangba, ọrọ nipa aabo to mẹhẹ ni. Ki i ṣe inu igbo niṣoro aisi aabo to n koju orileede yii wa. Oriṣii mẹrin niṣoro aisi aabo ta a n koju, ọkan ni ti awọn agbebọn rin lapa Ariwa, omi-in ni ti awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB n’Ila-Oorun si Guusu ti wọn n pera wọn ni ọmọ ẹgbẹ alaabo ESN (Eastern Security Network), awọn agbebọn naa si n yọ Ariwa/Iwọ-Oorun lẹnu. Aarin-Gbungbun Ariwa nikan lo n koju akọlu laarin awọn darandaran atawọn agbẹ. Akọlu awọn darandaran atawọn agbẹ diẹ lo wa ni Guusu/Iwọ-Oorun, afi tawọn ti wọn n pariwo idasilẹ Orileede Oodua.”

Alaga ẹgbẹ onimaaluu, MACBAN, ẹka ti Bauchi naa da sọrọ ọhun. Ọgbẹni Sadiq Ibrahim Ahmed ni “ọrọ yii ko ru’ju rara, o ti pẹ ti mọ ti n sọ ọ pe Naijiria maa fọ si wẹwẹ bi nnkan ṣe n lọ yii. Awọn adari wa ko nifẹẹ araalu mọ. Kawọn Fulani to ba wa lagbegbe wọn tete fibẹ silẹ o, ko ju bẹẹ lọ.”

Ṣugbọn Rotimi Akeredolu, to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina ipinlẹ Guusu Naijiria ti fesi pada sawọn atako ati ohun ti wọn n sọ naa. O ni ofin tawọn fẹnu ko le lori lati ma ṣe faaye gba fifi maaluu jẹko ni gbangba ki i ṣe ofin tuntun rara, tori ọkọọkan awọn gomina naa lo ti fofin de kinni ọhun ni ipinlẹ koowa wọn, tile-igbimọ aṣofin ipinlẹ kọọkan si ti fofin gba a nidii. Tori naa, niṣẹ ni kijọba apapọ ran awọn to ba fẹẹ ṣe papa ijẹko fun maaluu lọwọ, eyi si maa fopin si wahala akọlu laarin darandaran ati awọn agbẹ jake-jado agbegbe naa.

Awọn ipinlẹ mẹtadinlogun ti ọrọ ifofinde naa kan ni Eko, Ogun, Ọyọ, Ondo, Ekiti, Ọsun, Edo, Delta, Akwa Ibom, Anambra, Bayelsa, Ebonyi, Rivers, Enugu, Abia, Imo ati Cross-River.

Leave a Reply