Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Owurọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn mọlẹbi gbajumọ olorin Dadakuada nni, Jaigbade Alao kede iku rẹ to lo ọdun mọkanlelọgọfa (121), loke eepẹ.
Ọkan lara ọmọ baba naa to ba ALAROYE, sọrọ AbdulRazaq Jaigbade, sọ pe ko rẹ baba naa ra, sugbọn owurọ yii ni baba sọ pe ori n fọ awọn, ti wọn si ku lojiji ki wọn too gbe wọn lọ si ileewosan. O tẹsiwaju pe ọmọ mẹrinlelọgbọn (34), pẹlu iyawo mẹrin ni baba awọn fi saye lọ.
Aago mẹta ọsan ọjọ Aje, Mọnde, yii ni wọn yoo sin baba naa ni ilana Musulumi ni agboole Jaigbade, to wa ni agbegbe Ita mẹrin, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin (West).