Stephen Ajagbe, Ilorin
Agbẹ kan, Yusuf Igboona, to n gbe l’Oke-Igbọna, lagbegbe Banni, lo wọ maaluu kan lọ si agọ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ẹka ipinlẹ Kwara, nitori pe o jẹ oko iṣu rẹ.
Alukoro NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afọlabi, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2021, Yusuf fi to ileeṣẹ NSCDC to wa ni Banni leti pe awọn maaluu to jẹ ti Tijani Dogo, toun naa n gbe ilu Banni, wọnu oko iṣu oun tiye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogoji naira, ti wọn si jẹ gbogbo ẹ.
O ni Yusud gbiyanju, o si mu ọkan lara awọn maaluu naa, eyi to jẹ bii ẹri, lọ si tesan NSCDC lati fẹjọ sun.
Afọlabi ni awọn pe ọkunrin to da maaluu wọ oko naa lati gbọ tẹnu rẹ, loootọ lo jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun naa.
Yusuf ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira loun maa gba lọwọ ẹni to ni maaluu ọhun fun oko to jẹ, ṣugbọn Dogo bẹ ẹ lati gba ẹgbẹrun marundinlọgbọn lọwọ rẹ.
O ni lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, agbẹ naa pada gba owo ọhun lọwọ rẹ, bi awọn ṣe yanju ọrọ naa laarin wọn niyẹn.
Ileeṣẹ NSCDC ni igbesẹ tawọn gbe naa jẹ ọkan gboogi lara ojuṣe awọn, paapaa ti ẹka to n pẹtu saawọ laarin awọn agbẹ ati darandaran lati ri i pe alaafia jọba.