Agbegbe Guusu ni ipo aarẹ kan, ki i ṣe ilẹ Hausa-Fayoṣe

Jọkẹ Amọri

O jọ pe wahala to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ko ti i tan nilẹ, ọrọ si ti di bi adiyẹ da mi loogun nu, ma a fọ ọ lẹyin bayii pẹlu bi gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọ Fayoṣe, to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ṣe sọ pe ko si ohun to n jẹ pe ilẹ Hausa ni yoo tun fa aarẹ kalẹ lọdun to n bọ, o ni Iha Guusu ilẹ wa ni aarẹ gbọdọ ti wa.
Ọrọ to sọ yii ta ko ipinnu ẹgbẹ naa lati fa Alaaji Atiku Abubakar Atiku to jẹ ọmọ Hausa kalẹ lati jẹ oludije wọn, ti wọn si fi Ifeanyi Okowa to jẹ gomina Delta lati apa Guusu Guusu ilẹ wa ṣe igbakeji rẹ.
Ninu ọrọ kan to kọ sori ikanni Twita rẹ lo ti sọ pe ‘‘Saa keji ni ẹni to jẹ aarẹ ilẹ wa lọwọ bayii to wa lati ilẹ Hausa n lo lọ, ohun ti eyi tumọ si ni ipe iha Guusu ilẹ wa lo gbọdọ fa aarẹ kalẹ lọdun 2023. Ko si nnkan mi-in lẹyin eleyii. Awa South lo kan. Ki awọn ọmọ Naijiria maa reti ẹkunrẹrẹ alaye laipẹ.’’
Bẹẹ lo tun sọ pe ofin inu ẹgbẹ oṣelu PDP faaye gba jẹ ki emi jẹ, eyi to tumọ si pe ki wọn maa gbe ipo aarẹ yipo awọn ẹkun to wa ni orileede yii, ati pe ẹgbẹ gbọdọ tẹle ofin yii lai yẹsẹ.
Gbogbo awọn to ka ohun ti Fayoṣe sọ yii ni wọn sọ pe inu n bi ọkunrin naa si ẹgbẹ rẹ, iyẹn ẹgbẹ PDP. Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe ni ẹgbẹ naa dẹyẹ si i lasiko eto idibo gomina ti wọn di kọja yii nipinlẹ Ekiti, ti ẹni ti ọkunrin naa fa kalẹ, Bisi Kọlawọle, ko si rọwọ mu lasiko ibo naa. Wọn ni gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ to yẹ ko ṣatilẹyin fun un, to fi mọ oludije wọn sipo aarẹ ọdun to n bọ, Atiku Abubakar ni ko ṣatilẹyin fun un.
Ohun kan mi-in ti wọn lo tun n bi gomina tẹlẹ yii ninu ni bi wọn ko ṣe fa alatilẹyin rẹ, Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike, to ṣe ipo keji lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ naa sipo aarẹ kalẹ, to jẹ Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa ni wọn lọọ mu.
Awọn kan ti n gbe e pooyi ẹnu paapaa pe o ṣee ṣe ki Wike kuro ninu ẹgbẹ naa, to ba tiẹ wa nibẹ, ko ma ṣiṣẹ fun Atiku. Awọn eeyan kan sọ pe imura Wike lẹnu ọjọ mẹta yii pẹlu bo ṣe n wọ aṣọ Yoruba, to si n de fila Yoruba si i n foju ẹgbẹ to fẹẹ darapọ mọ bayii han.
Ko ti i sẹni to le sọ boya ọkunrin naa yoo kuro ninu ẹgbẹ PDP loootọ, ati ẹgbẹ to maa darapọ mọ to ba kuro nibẹ, nitori aipẹ yii naa lo ṣepade pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi. Ṣugbọn ohun to foju han ni pe inu n bi gomina naa si ẹgbẹ oṣelu rẹ, o si ṣee ṣe ko yọ ororo ohun ti wọn ṣe fun un l’Ekiti lara wọn.

Leave a Reply