Agbẹjọro to fọbẹ gbigbona jo ọmọ aburo ẹ lara tori ẹẹdẹgbẹta Naira ti dero ẹwọn

Faith Adebọla

 Tori ko sẹni ti ida ofin ko le ge, Abilekọ Aina Ọdetayọ, ẹni ọdun marundinlogoji, to n ṣiṣẹ lọọya ti dero atimọle ọgba ẹwọn, ile-ẹjọ Majisreeti lo paṣẹ bẹẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, latari ẹsun ti wọn fi kan obinrin naa pe ika ati ọdaju ẹda ni, wọn lo fi ọbẹ gbigbona jo ọmọ aburo ẹ lara, ọmọ ọdun mejila pere, o lo ji oun lowo.

Ẹsun mẹta ọtọọtọ, to da lori ṣiṣe akọlu si ọmọde, didọgbẹ si ni lara ati kikuna lati tọju ẹmi ọmọde ni wọn fi kan obinrin naa nile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Igbosere, lagbegbe Tinubu, l’Erekuṣu Eko, naa.

Agbefọba, Inpẹkitọ Micheal Unah ṣalaye pe Ojule kẹtala, Ẹsiteeti Green Hill, to wa l’Agege, ni Lọọya Ọdẹtayọ ati ọmọde to ṣe leṣe naa n gbe, ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ to kọja, lọjọ kẹrinla oṣu kọkanla yii niṣẹlẹ naa waye.

Unah sọ ni kootu pe: “Olujẹjọ yii ti kọkọ fibinu lu ọmọ ti o ti i toju u bọ yii lalubami lọjọ naa, latari ẹsun to fi kan an pe ọmọ ọhun lo maa ji oun lowo, ẹẹdẹgbẹta naira (N500), tori awọn meji naa lawọn jọ n gbe, lẹyin eyi lafurasi ọdaran yii fi ọbẹ sori ina gaasi ẹ, lo ba fi ọbẹ gigbona naa jo ọmọ ọlọmọ lara kaakiri.

Ati pe lẹyin ti ọmọ naa n kerora, to n joro ọgbẹ buruku yii, afurasi ọdaran yii taku lati gbe e lọ sọsibitu fun itọju iṣegun, o lo gbọdọ jiya ẹṣẹ ẹ daadaa.”

Oluwa mi, awọn ẹsun ta a fi kan afurasi ọdaran yii ta ko isọri kẹwaa, ikejila ati ikẹtala iwe ofin ẹtọ awọn ọmọde nipinlẹ Eko, ti wọn ṣe lọdun 2019.”

Olujẹjọ naa sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun mẹta ti wọn fi kan oun, o loun ni alaye lati ṣe.

Adajọ kootu naa, Ọgbẹni Azeez Alogba, ni ki wọn fi afurasi ọdaran naa si ọgba ẹwọn, ṣugbọn o faaye beeli silẹ fun un to ba mu iwe aṣẹ to fi n ṣiṣẹ lọọya wa, ati oniduro meji. Obinrin naa niwee-aṣẹ oun ko si nitosi, lo fi dero ẹwọn.

Leave a Reply