Dada Ajikanje
Agbẹnusọ Aarẹ Buhari lori eto iroyin, Garba Sheu, ti tọrọ aforiji lori ọrọ ti oun sọ pe awọn akẹkọọ mẹwaa pere lo sọnu nileewe Kankara, nipinlẹ Katsina, lọsẹ to kọja.
Garba ni ẹni to yẹ ko mọ nipa iṣẹlẹ naa to sọrọ yii foun lo ṣi oun lọna. O ni oun ko lo ikede naa lati le din pataki iṣẹlẹ naa ku rara.
‘‘Ẹ jọwọ, ẹ gba aforiji ti mo tọrọ lori ọrọ yii, bi a ti n gbiyanju lati mu itẹsiwaju ba ilẹ wa. Ẹ ṣeun’’ Garba lo sọ bẹẹ.
Tẹ o ba gbagbe, Garba ti kọkọ sọ nibi ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Hausa pe irọ ni awọn eeyan n pa pe akẹkọọ to sọnu le ni ọọdunrun, o ni awọn mẹwaa pere ni wọn ṣi n wa.
Afi bi Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari ṣe jade sita, toun si sọ pe awọn akẹkọọ to lẹ mẹtalelọgbọn ni ọọdunrun ni wọn ko ti i ri.
Nigba ti aṣiri ọrọ naa yoo pada tu, aọn akẹkọọ ti wọn ri gba pada tun le mẹwaa si iye ti gomina Katsina funra ẹ pe wọn.