Jide Kazeem
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi, ti sọ pe ki Rotimi Akeredolu atawọn ti wọn jọ n ṣejọba lọọ sinmi ariwo, oun ko ni i kọwe fipo silẹ rara, niṣe lawọn yoo jọ pari saa yii lọdun to n bọ.
Ẹgbe oṣelu Zenith Labour Party ni Ọnarebu Agboọla Ajayi lọ ni kete ti ipalẹmọ eto idibo to waye lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii bẹrẹ, ṣugbọn to fidi rẹmi, ti Akeredolu ni tiẹ si pada sipo gomina.
Latigba ti Akeredolu to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ti wọle pada ni awuyewuye kọwe-fipo silẹ yii ti wa laarin awọn mejeeji.
Nibi ifọrọwerọ kan ti Gomina Akeredolu ṣe ni kete to jawe olubori lo ti kọkọ sọ pe ti igbakeji oun ba jẹ ẹni to lojuti, niṣe lo yẹ ko fipo ẹ silẹ gẹgẹ bii igbakeji gomina. Bakan naa lo sọ pe oun ṣetan lati fa a mọra ti o ba ronupiwada.
Ajayi ni tiẹ ti sọ pe wọn o ba a pariwo ju bẹẹ lọ, oun yoo wa lori ipo ni titi ti saa ti awọn jọ gba iwe-ẹri ẹ lọdun 2016 yoo fi pari ni.
Allen Soworẹ, ẹni ti i ṣe amugbalẹgbẹẹ fun Agboọla Ajayi lo sọ pe ọkunrin naa ko ṣetan lati kọwe fipo silẹ rara, ati pe awọn ti wọn n sọ bẹẹ kiri, isọkusọ ni wọn n sọ. O ni, “O di ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun to n bọ yii, nigba ti saa ijọba to n lọ lọwọ l’Ondo ba pari, nigba yẹn gan-an ni Ọnarebu Ajayi yoo too kuro gẹgẹ bii igbakeji gomina ipinlẹ Ondo ti a dibo yan.