Ajẹ n’iya wa, ogo mi lo gbe fun Mercy Aigbe – Patience

Faith Adebọla, Eko

 Titi dasiko yii ni ọpọ awọn ololufẹ gbaju-gbaja arẹwa oṣere tiata ilẹ wa nni, Mercy Aigbe, atawọn ẹlomi-in to gbọ nipa iṣẹlẹ naa n ṣe kayeefi pe iru ibinu wo lo le mu ki ẹgbọn lọọ dana sun ile iya wọn tori aburo rẹ, ọpọ lo si gba pe ejo ọrọ yii lọwọ ninu.

Ṣe ọrọ ni i ba mo-ko-mo-ro wa, eegun to si ti bọ sita ti kuro ni aiwo-o, latigba tafẹfẹ ọrọ naa ti gori ẹrọ ayelujara lo ti n ja ranyin, latari bi ẹgbọn Mercy Aigbe, Abilekọ Patience, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) ṣe lọọ fibinu sọ ina si ile mama wọn to wa ni Opopona Adebayọ Mokuolu, nidojukọ Anthony Village Recreation Center, niluu Eko, wọn lo fẹsun kan aburo ẹ, Mercy, pe gbogbo ọla ati gbajumọ rẹ ko ṣẹyin mama awọn, o ni ajẹ ni mama naa, ati pe iṣẹ ajẹ rẹ lo fi gba ogo oun fun aburo oun, o niyaa naa lo pa kadara oun da.

Wọn lobinrin to n ṣiṣẹ dokita alabẹrẹ yii tun fẹsun kan iya naa pe o ri gbogbo iya to n jẹ oun, ṣugbọn ko ṣe bii abiyamọ gidi lori oun rara, Mercy lo n gbọn tẹle lẹyin kiri, o loun nilo ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (N800,000), lati fi san gbese gọbọi kan toun jẹ, oun si parọwa si mama awọn lati ran oun lọwọ, ṣugbọn mama naa ko da oun loun.

Ba a ṣe gbọ, apa kan lara ile ti ọkọ iya wọn fi silẹ gẹgẹ bii ogun fun mama agbalagba ọhun ati iyekan wọn, iyẹn ọmọkunrin kan ṣoṣo tiyaa wọn bi f’oloogbe, lẹgbọn Mercy dana sun yii. Fulaati oniyara meji kan nile ọhun, wọn kọ ọ sọtọ ni, bo tilẹ jẹ pe awọn fulaati mi-in tun wa ninu ọgba naa to jẹ tawọn orogun Iya Mercy atawọn ọmọ wọn.

Wọn lọpẹlọpẹ akitiyan awọn panapana ti wọn wa sibi iṣẹlẹ ọjọ naa atawọn aladuugbo ti wọn ṣeranwọ, ni ko jẹ k’ina naa ran mọle mi-in, ati ileewe awọn ogo wẹẹrẹ kan to wa nitosi wọn.

Oniroyin ẹrọ ayelujara kan, Gistlover, sọ pe ija yii ti bẹrẹ tipẹ, ina rẹ ti n ru bọ latilẹ ko too debi to de yii. O lafurasi ọdaran naa ti kọkọ wa sile ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to lọ, tibinu-tibinu lo fi wa, ṣugbọn ko ba mama rẹ nile, iya ti lọ sọdọ Mercy, lo ba yọ irin kan tọwọ ẹ ba, o bẹrẹ si i fọ gilaasi windo ile naa, o ba gbogbo ẹ jẹ, o tun ba ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna alawọ buluu kan to jẹ ti mama rẹ ọhun jẹ, o fọ gbogbo gilaasi, ina iwaju ati ina ẹyin ọkọ naa, o si pada lọ.

Eyi ni wọn ṣi n sọ lọwọ ko too tun pada wa lọjọ Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa yii, awọn tọrọ ọhun ṣoju rẹ ni bo ṣe de, taara lo kọja soju windo to bajẹ lọjọsi, lati ferese naa lo ti bu bẹntiroolu sinu ile, o si sọna si i. Wọn ni bo ṣe n huwa ọdaran naa lo n leri pọn-ọn-ran-pọn pe iya oṣi niyaa awọn, oun loun maa rẹyin ẹ, tori ajẹ ni,  irawọ ati ogo oun lo gbe fabuuro oun, oun o si ni i gba, eyi toun ti n woran wọn ti to gẹẹ.

Lẹyin to ṣe gbogbo eyi tan ni wọn lo gba teṣan ọlọpaa lọ, o lọọ fẹjọ ara ẹ sun, o ṣalaye itu toun ṣẹṣẹ pa fun wọn, ni wọn ba mu un satimọle.

Mercy Aigbe ati iya wọn ọhun ti ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ yii, ọkọ jiipu bọginni dudu kan ni wọn gun wa, wọn rin yipo ile naa lati ri iwa basejẹ ti Patience hu, wọn si lọ pẹlu ikoro oju.

Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, gbogbo igbiyanju wa lati ba Mercy Aigbe sọrọ lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo, tori ko gbe aago rẹ, bẹẹ ni ko fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ sori ikanni Wasaapu rẹ.

Ninu ọrọ tawọn aladuugbo sọ nipa iṣẹlẹ naa, wọn ni onigbonara ati ojowu ẹda kan ni ẹgbọn Mercy Aigbe yii, wọn lo tọrọ owo lọwọ aburo rẹ, tiyẹn ko si fun un lo da ọta silẹ laarin wọn, ati pe Mercy Aigbe lo mu mama rẹ sọdọ nigba ti afurasi ọdaran yii n dunkooko mọ ẹmi iya wọn.

Ṣa, a gbọ p’awọn agbofinro ti n ṣewadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply