Ajibọla ki ọmọbinrin kan mọlẹ ninu ṣọọṣi, lo ba fipa ba a lo pọ n’Ita-Ọṣin

Gbenga Amos, Abeokuta
Akolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni gende ẹni ọgbọn ọdun kan, Ajibọla Akindele, wa lasiko yii, ọmọbinrin ẹni ogun ọdun kan lo fipa ba lo pọ, ibi ti ko bọ si i rara lo si ti ṣe kinni ọhun, inu ṣọọṣi lo ti lọọ huwa aidaa fọmọọlọmọ.
Alukoro ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, lafurasi naa huwa ọdaran ọhun.
Iya ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa lo lọọ fẹjọ sun ni tọlọpaa, o ni ipalẹmọ ati dẹkoreṣan tawọn maa n ṣe lọsọọsẹ fun eto isin ọjọ isinmi to maa waye lọjọ keji loun ni kọmọ oun lọọ ṣe ni ṣọọṣi ti wọn o fẹẹ darukọ to wa lagbegbe Ita-Ọṣin, niluu Abẹokuta.
O lọmọ oun sọ pe nigba toun debẹ, oun ba awọn obinrin mi-in ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ, wọn n ṣe imọtoto ati atunṣe ileejọsin naa, ṣugbọn ko pẹ tawọn yẹn fi kuro nibẹ nigba ti wọn ti pari iṣẹ ti wọn n ṣe.
Bo ṣe di pe Ajibọla wọle lọọ ba ọmọbinrin naa niyẹn, lo ba ki i mọlẹ, o si fipa ba a sun.
Bi DPO ọlọpaa Lafẹnwa ṣe gbọrọ yii lo ti da awọn ọmọọṣẹ ẹ sita ki wọn wa afurasi naa lawaakan, ṣugbọn oun naa kọkọ sa lọ, ọjọ kẹta ni wọn too ri i mu.
Ajibọla jẹwọ ni teṣan pe loootọ loun huwa buruku ọhun, o ni ki wọn ṣaanu oun.
Ṣugbọn Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari ẹ sẹka ti wọn ti wọn n tọpinpin iwa ọdaran abẹle ati ifipabanilopọ lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweẹran. Ibẹ ni wọn ni yoo gba dele-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply