Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu kẹjọ yii, gboro loju ọna Ibeṣe-Itori, nipinlẹ Ogun, nigba ti awọn ajinigbe agbebọn dena de ọkunrin kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Swiss, ti wọn ji i gbe lọ pẹlu dẹrẹba rẹ, ti wọn si yinbọn mọ meji ninu awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ti oyinbo yii n ṣiṣẹ fun, ti ọkan pada dagbere faye ninu wọn.
Wahala ọhun ko mọ bẹẹ, o pada di ohun ti awọn ọlọpaa le awọn ajinigbe naa wọgbẹ, ti wọn pa meji ninu wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, ṣe sọ.
Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bawọn eeyan agbegbe naa ṣe ṣalaye ni pe ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Satide naa, oyinbo ọmọ ilẹ Swiss torukọ ẹ n jẹ Andred Beita lawọn ajinigbe naa fẹẹ ji gbe.
Awọn oṣiṣẹ to n ba alaga ileeṣẹ Olabel Farms toyinbo n ṣiṣẹ fun wa ninu ọkọ pẹlu rẹ, wọn n bọ lati Ilaro, wọn si fi ọlọpaa kan ti wọn ninu mọto naa lati maa ṣọ Andred Beita.
Nigba ti wọn de oju ọna Itori-Ibeṣe ni awọn ajinigbe to ti dena de wọn ya bo wọn lojiji, wọn si doju ija kọ wọn nigba ti wọn ri i pe ọlọpaa wa ninu ọkọ naa to n ṣọ oyinbo yii.
Awọn ajinigbe naa yinbọn titi, wọn gbe oyinbo Swiss lọ, wọn si gbe awakọ rẹ ti wọn pe ni Ifeanyi naa lọ pẹlu.
Ibọn ti wọn n yin naa ba meji ninu awọn to wa ninu ọkọ pẹlu oyinbo, orukọ wọn ni Ishaya Ibrahim ati Micheal Kujọrẹ. Wọn sare gbe wọn lọ sileewosan fun itọju, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ fun Micheal Kujọrẹ, oun pada ku ni.
Nigba to n ṣalaye f’AKEDE AGBAYE laaarọ ọjọ keji iṣẹlẹ naa nipa bi Micheal ṣe pada ku, Alukoro ọlọpaa Ogun sọ pe ọsibitu mẹrin ni wọn ti gbe e lọ fun itọju ti wọn ko gba a, ti wọn n sọ pe ko si bẹẹdi ti wọn yoo gba alaisan si lati tọju rẹ. Lẹyin igba naa ni ọkunrin naa dagbere faye.
Ikeji rẹ, Ishaya Ibrahim, ṣi n gbatọju lọsibitu ti wọn gbe e lọ n’Ilaro. Oyeyẹmi tẹsiwaju pe awọn agbebọn naa ko lọ bẹẹ, o ni awọn ọlọpaa pa meji mu ninu wọn, wọn si ri ibọn AK 47 kan gba lọwọ wọn pẹlu. O lawọn ṣi n dọdẹ awọn ajinigbe naa lati ri wọn mu, bẹẹ ni wọn ko ti i beere owo idande awọn ti wọn ji gbe naa bi iṣe wọn.