Nitori ọkunrin, Joy da omi gbigbona le Justina lori l’Agbado

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi oju apa yoo ṣe jọ oju ara fun iyawo ile kan torukọ ẹ n jẹ Justina Ameh, ko ti i ye ẹnikẹni bayii, idi ni pe obinrin bii tiẹ, Joy Sunday, ti da omi gbigbo le e lori, gbogbo oju ati ẹnu rẹ lo ti bo torotoro, to si wu kungbun-kungbun, bẹẹ, ọrọ ọkunrin lo fa a.

Ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni Joy to da omi gbigbona le Justina lori yii, obinrin naa ti bimọ meji, ṣugbọn ko si nile ọkọ. Justina wa nile ọkọ ni tiẹ, ẹsun kan naa to si maa n fi kan Justina ni pe o n yan ọkọ oun lale. Agbado, nipinlẹ Ogun, ni gbogbo wọn jọ n gbe.

Ṣugbọn lọjọ ti Joy yoo fi opin si ẹsun ti Justina fi n kan an yii, inu ṣọọṣi lo ti lọọ da omi gbigbona lu u, lasiko ti iṣọ oru n lọ lọwọ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun fi sita, ẹgbọn Justina lo lọọ fi to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Agbado, pe Joy ti da omi gbigbona le aburo oun lori ninu ṣọọṣi o, koda, o fi ọbẹ gun oun paapaa lọwọ nibi toun ti di i mu pe ko ma ṣe aburo oun jamba.

Awọn ọlọpaa debẹ, wọn ba Joy to ṣoju konko lẹyin iṣẹ laabi naa, wọn si mu un.

Nigba to n ṣalaye idi ẹ to fi da omi gbigbona le Justina lori, obinrin ọlọmọ meji ti ko lọkọ yii sọ pe Justina ko ṣẹṣẹ maa fi ẹsun kan oun pe oun n yan ọkọ rẹ lale, bẹẹ, ko si kinni kan to da oun ati ọkọ re pọ.

O ni ko too di pe oun lọọ gbe omi gbigbona waa ba a ni ṣọọṣi yii, iyẹn ṣọọṣi ‘Spring of Life Global Ministry’, to wa ni Giwa, Agbado, o ni niṣe ni Justina n rọjo epe le oun lori ninu ṣọọṣi.

Joy tẹsiwaju pe oun ko da a lohun, oun rin kuro lọdọ rẹ lati yago fun Eṣu, ṣugbọn niṣe lo tun fa oun pada to si fa aṣọ oun ya.

Obinrin naa sọ pe oun to bi oun ninu ree, toun fi lọ sile lati gbe omi kana, bo si ti ho loun gbe e sinu ibi ti ko ti ni i tutu, boun ṣe de ọdọ Justina to n parọ mọ oun loun da a le lori.

Awọn ọlọpaa beere pe ṣe loootọ lo n fẹ ọkọ Justina, Joy ni rara, oun ko fẹ ọkọ rẹ, ko si sohun toun ko le fi bura si i.

Ṣa, wọn ti gbe iya ọlọmọ meji yii ju satimọle, ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, si ti ni ki wọn ṣewadii ẹ daadaa.

Justina wa nileewosan Strong Tower ni tiẹ, o n gba itọju ti oju rẹ yoo fi pada si tatijọ.

Leave a Reply