Fulani ajinigbe mẹta ko sọwọ ọlọpaa n’Imẹkọ

Gbenga Amos, Ogun

Ọwọ palaba awọn afurasi ajinigbe mẹta ti segi lagbegbe Yewa, nipinlẹ Ogun, ọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn, wọn si ti sọ wọn sahaamọ.

Inu igbo kijikiji kan to wa lọna Imẹkọ si Iwoye-Ketu, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn, lọwọ ti ba awọn ọdaju oniṣẹẹbi naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii. Orukọ wọn ni Aliu Abubakar, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Umaru Tukur, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Yau Isah, toun jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

SP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an ta a wa yii pe, awọn kan ni wọn pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ilu Imẹkọ nipe pajawiri lọsẹ to kọja, wọn lawọn ajinigbe bii mẹjọ kan ti gbegi dina lọna Termac si Iwoye pẹlu oriṣiiriṣii nnkan ija oloro ti wọn ko dani, wọn yinbọn fawọn eeyan meji, Ọgbẹni Bọde Ogunlẹyẹ ati Muhammad Basa, wọn ko ku, ṣugbọn wọn ṣeṣe gidi, wọn si ji awọn mẹta gbe wọ’gbo lọ.

Orukọ awọn ti wọn ji gbe naa ni Alaaji Fatai Animaṣawun, Alaaji Dauda Orelope ati Alaaji Rafiu Isah.

Oju-ẹsẹ tawọn ọlọpaa gba ipe yii ni DPO teṣan Imẹkọ ti ke sawọn ọmọọṣẹ ẹ, wọn ranṣẹ pe awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ati SO-SAFE, wọn ke sawọn ọlọdẹ naa, awọn fijilante atawọn ọdọ to lọkan akin laarin awọn Yoruba ati Fulani ti wọn n gbe lagbegbe naa, gbogbo wọn ni wọn ta mọra, tori agan lọrọ to delẹ ọhun, afi ki wọn jọ gbe e.

Wọn ni bi gbogbo wọn ṣe pin ara wọn si isọri isọri yika igbo naa, wọn bẹrẹ si i fọ inu igbo ọhun, wọn n tọpasẹ awọn ajinigbe naa lọ, nigba tawọn eeyankeeyan naa roye ohun to n ṣẹlẹ, ẹru ba wọn, ni wọn ba fi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa silẹ sidii igi kan ninu igbo nla naa, wọn tun fi ọkada kan silẹ nibẹ, ṣe oju ina kọ l’ewura n hu’run, kia ni wọn bẹsẹ wọn sọrọ, ere lẹẹ lẹẹ lẹẹ lẹsẹ wọn.

Awọn ọlọpaa ko awọn ti wọn ji gbe naa jade, ko sẹni to fara pa ninu wọn, wọn si wọ ọkada ti ko ni nọmba naa lọọ si teṣan. Awọn ẹṣọ yooku n ba iṣẹ lọ ninu igbo ni tiwọn, boya ọwọ wọn le tẹ awọn amookunṣika naa.

Nigbẹyin, wọn ri awọn mẹta mu, wọn ba kọkọrọ ọkada Bajaj ti wọn fi silẹ naa ninu apo ọkan ninu wọn, wọn si ri awọn nnkan ija ti wọn ko dani bii ọbẹ aṣooro ati ada. Wọn jẹwọ pe awọn yooku wọn ti sa lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn afurasi naa ati ẹsibiiti wọn sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti iwa ijinigbe nipinlẹ Ogun, iṣẹ iwadii to lọọrin si ti n lọ lọwọ.

Leave a Reply