Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii ti kede ipinnu wọn lati ṣafikun si awọn ibudo idibo to wa nipinlẹ Ondo tẹlẹ.
Alaboojuto fun ajọ naa nipinlẹ Ondo, Ambasadọ Rufus Akẹju, lo sọ eyi ninu ipade kan to ṣe pẹlu awọn tọrọ kan ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
O ni ibudo idibo tuntun bii ẹẹdẹgbẹrun ati okoo le mẹrin (924) ni wọn fẹẹ fi kun ẹgbẹrun mẹta o le mẹsan-an to ti wa nilẹ tẹlẹ, ti apapọ gbogbo ojuko idibo ti yoo wa nipinlẹ Ondo yoo si jẹ ẹgbẹrun mẹta ati oji le lẹẹẹdẹgbẹrun din meje (3,933)
Akẹju ni ọkan-o-jọkan iwe ẹhonu lawọn araalu n kọ sawọn lati bii ọdun marundinlọgbọn sẹyin lori ẹsun pe awọn n fẹtọ awọn eeyan dun wọn lasiko ti eto idibo bá ń lọ lọwọ latari bi awọn ibudo idibo to yẹ ki wọn ti ṣe ojuṣe wọn ko ṣe si nitosi ibugbe wọn.
O ni oun nigbagbọ pe afikun tuntun naa yoo fopin si gbogbo awuyewuye to maa n waye lori bi ero ṣe maa n pọ ju ohun eelo lọ lasiko atawọn oludibo ba n forukọ silẹ lati gba kaadi idibo.
O ni iṣẹ tí n lọ labẹlẹ lori abajade iwadii ti ajọ eleto idibo ni ki awọn oṣiṣẹ rẹ kan lọọ ṣe lori igbesẹ naa bẹẹ lo fi da awọn eeyan ipinlẹ Ondo loju pe gbogbo ibudo ibudo idibo tuntun naa ni yoo fara han nínu iwe ti wọn fẹẹ fi ṣe iforukọsilẹ awọn oludibo, eyi ti wọn fẹẹ bẹrẹ laipẹ.