Faith Adebọla
“Laarin ọsẹ mẹta pere ọfiisi ileeṣẹ wa meje ni wọn kọ lu. Wọn dana sun marun-un, wọn si jalẹkun, wọn si ṣe ibẹ baṣubaṣu. Ipinlẹ Abia, Akwa Ibom, Enugu ati Ebonyi lawọn iṣẹlẹ naa ti waye. A o mọ ero ọkan awọn ti wọn wa nidii akọlu wọnyi to fi jẹ ileeṣẹ INEC ni wọn doju sọ lasiko yii. Ṣugbọn ohun to daju ni pe ti iwa basejẹ yii o ba duro, ko sọgbọn ko ma ṣakoba fun awọn eto idibo to n bọ lọna.”
Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, alaga ajọ INEC (Independent National Electoral Commission), iyẹn ajọ eleto idibo ilẹ wa ṣe sọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, niluu Abuja, nigba to n sọrọ nipa awọn akọlu to waye si awọn ọfiisi ajọ naa lawọn ipinlẹ kan nilẹ Ibo laipẹ yii.
Eyi to kẹyin ninu akọlu naa ni ọfiisi INEC meji ti wọn lawọn ọbayejẹ ẹda kan dana sun lafẹmọju Ọjọruu, Wẹsidee yii, nipinlẹ Ebonyi. Ọfiisi INEC to wa nijọba ibilẹ Ariwa Ezza, ateyi to wa nijọba ibilẹ Izzi, niṣẹlẹ naa ti waye.
Ṣaaju ni Alukoro ajọ INEC, Ọgbẹni Cornelius Alli, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin ni Abakaliki, o lawọn janduku to ṣakọlu naa dana sun awọn aga onipako ti wọn fi n dibo, awọn jẹnẹretọ, ati awọn iwe idibo atawọn dukia olowo iyebiye to wa lawọn ọfiisi ọhun.
Alaga ajọ INEC ni awọn ti bẹrẹ si i fori kori pẹlu awọn agbofinro lati ṣeto aabo to gbopọn fun ajọ ọhun, ati lati wadii ohun to fa akọlu lemọlemọ ọhun.
O ni yatọ sawọn dukia to ṣegbe, ọpọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni wọn ti wa ninu ibẹru bayii, eyi si le nipa lori agbara wọn lati ṣe ojuṣe wọn lai si ifoya.
O bẹnu atẹ lu iwa basejẹ naa, o si parọwa sawọn araalu lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn agbofinro, pe ki wọn tete maa ta wọn lolobo ti wọn ba ti kẹẹfin awọn ọbayejẹ ti wọn fẹẹ ṣakọlu si nnkan ini ijọba.