Ọdọ ọrẹ ni Lukman ti n bọ tawọn agbebọn fi yinbọn pa a ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọkunrin kan, Lukman Owolabi, lo pade iku airotẹlẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lagbegbe Oju-ẹkun, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe awọn ẹru iku naa lepa Lukman de adugbo rẹ, ṣugbọn nigba ti ẹnikan to n jẹ Gafaru Aladi n gbiyanju lati gba a silẹ loun naa fara gba ọta.

Nnkan bii aago mọkanla alẹ lawọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe o ṣẹlẹ. Ko sẹni to mọ pato ohun to da wahala silẹ laarin ọkunrin naa atawọn to waa fi ibọn ka a mọle ọhun.

ALAROYE gbọ pe lasiko tiyẹn n pada bọ lati ọdọ ọrẹ rẹ kan to lọọ ki lawọn agbebọn ti wọn fura si pe wọn jẹ agbanipa naa tẹle e debi ti wọn ti yinbọn fun un.

Ile akọku kan ni wọn ni Lukman kọkọ fara pamọ si nigba to ri wọn. Inu ibẹ gan-an ni wọn pada ka a mọ, ti wọn si pa a si.

A gbọ pe wọn ti sinku rẹ nilana Musulumi.

Ṣugbọn, nigba ti akọroyin wa kan si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, o loun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa. O ṣeleri lati ṣewadii.

 

Leave a Reply