Ọlọpaa ti mu Marcus, ile onile lo lọọ fọ n’Ikọtun

Faith Adebọla, Eko

Boya ọkan awọn olugbe Ikọtun si Igando yoo balẹ diẹ wayi, pẹlu bọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ ogbologboo fọlefọle kan, Marcus Ikechukwu, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ti wọn loun ni ko jẹ kawọn eeyan adugbo naa sun asunwọra, latari bo ṣe n fọle, to si n ji wọn lẹru ko sa lọ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, lawọn ọlọpaa ni ọwọ awọn ba ọmọ oru-la-a-ṣika ẹda yii, wọn lo ti pe ti okiki ẹ ti n kan lagbegbe Ikọtun, Igando, ati Surulere, nipinlẹ Eko, awọn ọlọpaa si ti n dọdẹ rẹ, ṣugbọn to jẹ bo ba ku diẹ kọwọ ba a lo n dawati.

Wọn ni bi ikun ṣe fẹran ẹpa to bẹẹ lọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Imo to loun n gbe adugbo Karabosowa, lagbegbe Ọjọọ, Alaba, yii fẹran lati maa fọ ilẹkun ṣọọbu awọn ọlọja lọganjọ oru, ti yoo si ko wọn lẹru ati owo sa lọ.

Awọn ọlọpaa to n lọ kaakiri ọja Alaba International Market, ni wọn fura si bọọsi Toyota alawọ ewe kan lọjọ Iṣẹgun ọhun, ni wọn ba da a duro lati wo ẹru to wa ninu ẹ.

Wọn ni bi wọn ṣe n tu ẹru naa, wọn ba awọn foonu loriṣiiriṣii atawọn dukia mi-in, ẹrọ amunawa (jẹneretọ) nla mẹta ti ko ni ẹri pe oun lo ni wọn, wọn si tun ri ẹrọ ti wọn fi n ge irin ati atawọn nnkan eelo ti wọn fura si pe oun ni lafurasi ọdaran naa fi n ja ṣọọbu oniṣọọbu.

Nigba ti wọn yẹ ara ẹ wo, wọn ri i pe o lẹbọ lẹru, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e. Wọn lọkunrin naa ti jẹwọ ni teṣan wọn pe oun fọ ṣọọbu lọọ ji awọn dukia naa ni, o ni ẹẹkan naa kọ loun ji awọn jẹneretọ mẹtẹẹta o, ati pe ibi toun fẹẹ ta a si loun n ko wọn lọ tọwọ fi ba oun yii.

Ṣa, wọn ti fiṣẹlẹ yii to kọmiṣanna ọlọpaa Eko leti, o si ti ni ki wọn taari Marcus sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba. Ibẹ lo wa bayii, to n fara balẹ dahun awọn ibeere wọn.

Leave a Reply