Ọlawale Ajao, Ibadan
Ajọ Yoruba World Centre (WYC), iyẹn ajọ Yoruba Agbaye, ti ṣeleri lati ran ijọba apapọ lọwọ lori ilana eto ẹkọ tuntun to gbe kalẹ.
Ninu lẹta ikini-ku-oriire ti ajọ naa kọ si Minisita fun eto ẹkọ lorileede yii, Mallam Adamu Adamu, ni wọn ti ṣeleri ọhun.
Kiki ti ajọ YWC ki minisita feto ẹkọ kuu oriire ko ṣẹyin bi ijọba apapọ ṣe tẹwọ gba aba to da, pe ki wọn maa fi ede abinibi kọ awọn akẹkọọ lati iwe kinni de iwe kẹfa.
Aarẹ orilee yii, Aarẹ Muhammadu Buhari, funra rẹ lo kede ilana tuntun naa ninu ipade igbimọ alaṣẹ to dari l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Ninu lẹta ọhun, eyi ti oludari agba ajọ naa, Ọgbẹni Alao Adedayọ funra rẹ kọ si Mallam Adamu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, lajọ YWC ti ṣapejuwe ofin ilana eto ẹkọ tuntun to pọn ọn ni dandan fawọn alaṣẹ ileewe gbogbo lati maa fi ede abinibi kọ awọn akẹkọọ ileewee alakọọbẹrẹ lẹkọọ gbogbo gẹgẹ bii aṣeyọri fun minisita naa lasiko to wa lori aleefa.
O waa rọ ẹni gbogbo ti ọrọ ọhun ba kan gbọngbọn lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba atawọn alaṣẹ eto ẹkọ lati ri i pe eto naa kẹsẹ jari.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Eyi to ohun to yẹ ka maa dunnu le lori nitori igbesẹ to n sọ orileede di giga ni Naijiria ṣẹṣẹ gbe yii gẹgẹ bii awọn orileede to ti laamilaaka lorilẹ aye naa ti ṣe ṣe ṣaaju.
“Lilo ede abinibi lati maa fi kọ awọn ọmọ lẹkọọ lati kekere ti ran ọpọlọpọ orileede agbaye lọwọ lati ni idagbasoke, bẹẹ, lara ohun to jẹ ipenija fun awa lẹka eto ẹkọ ree, nitori bi wọn ṣe n fi ede atọhunrinwa kọ awọn ọmọ wa, lawọn wọnyi n nifẹẹ aṣa ati irori ilẹ okeere, ti wọn si n fojoojumọ koriira aṣa ati ohunkohun to ba jẹ mọ nnkan ibilẹ tiwọn titi dori ilu ati orileede wọn paapaa.
“Lọdọ tiwa, ni Yoruba World Centre, a ti
pinnu lati lo ohun gbogbo to wa ni ikapa wa
pẹlu pipe gbogbo awọn to ba ni nnkan i ṣe lẹka eto ẹkọ jọ lati ri i daju pe gbogbo wa la kopa to yẹ, ki ilana eto ẹkọ tuntun yii le kẹsẹ jari’.