Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Oludamoran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ oṣelu, Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, ti sọ pe ko si aaye fun ẹnikẹni to n huwa bii ọmọọdọ lati jẹ gomina Ekiti lọdun 2022 latinu ẹgbẹ All Progressives Congress (APC).
Ojudu ni gbogbo ọna ni APC yoo fi koju People’s Democratic Party lasiko idibo gomina to n bọ ọhun, ṣugbọn APC ko ni i gba ẹni ti yoo maa huwa ọmọọdọ, ti ko si ni i duro sipinlẹ naa lasiko iṣejọba.
Sẹnetọ tẹlẹ ọhun sọrọ yii lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ni Wọọdu Kẹjọ, Ereguru, l’Ado-Ekiti, lasiko to n forukọ silẹ nibi eto iforukọsilẹ ti APC n ṣe lọwọ.
Ojudu sọ siwaju pe ko si wahala laarin oun ati Gomina Kayọde Fayẹmi, ọrọ oṣelu lo kan n fa ariyanjiyan, ṣugbọn ọmọ ẹgbẹ lawọn. O ni bi oun ko ṣe lagbara lati le gomina naa kuro lẹgbẹ loun naa ko le le oun.
O ni, ‘‘Mo fẹẹ fi da yin loju pe ko si ẹnikan ti yoo gbe gomina le wa lori ni 2022. Gbogbo ọmọ ẹgbẹ yii ni yoo lẹtọọ lati dije nibi ibo abẹle, bẹẹ ni ilana dẹmokiresi ni yoo bori.
‘‘A ko fẹ ajoji tabi ẹni ti yoo maa ṣe ọmọọdọ fawọn kan.’’
O fi kun un pe igba diẹ leeyan maa n lo nipo agbara, idi niyi ti Ekiti fi nilo ẹni to ko eeyan mọra, to si n duro siluu, ki i ṣe ẹni to n sa kiri tabi to jinna sawọn eeyan.
Lori pe minisita tẹlẹ nilẹ yii, Fẹmi Fani-Kayọde, n bọ ni APC, Ojudu ni ko si nnkan toloṣelu naa fẹẹ waa ṣe, ko jokoo sibi to wa. O ni ẹnikan ko le deede maa bu aarẹ ati igbakeji aarẹ ko tun fẹẹ wa si ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa.