Faith Adebọla, Eko
Iwadii to lọọrin gidi lo n lọ lọwọ lori ọmọbinrin akẹkọọ Fasiti Eko, ẹni ọdun mọkanlelogun, Chidinma Adaora Ojukwu, ti wọn fẹsun kan, to si ti jẹwọ pe loootọ loun gun ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV, Ọgbẹni Osifo Ataga, lọbẹ pa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn ti bẹrẹ si i ṣakojọ oriṣiiriṣii ọrọ to n tẹ awọn lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun, awọn si ti n ko o jọ fawọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn mọ nipa ifọsiwẹwẹ awọn iroyin iwa ọdaran, lati tubọ tọpinpin lori iṣẹlẹ ọhun.
Agbẹnusọ funleeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, fidi ẹ mulẹ fun AKEDE AGBAYE pe awọn ti ẹka tuntun kan ti Kọmisanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ṣẹṣẹ da silẹ, nibi ti wọn ti n lo imọ ẹrọ igbalode atawọn irinṣẹ kọmputa lati fi ṣewadii lawọn fa iṣẹ naa le lọwo, wọn si ti ko si i lọgan.
Panti, ni Yaba, lẹka ọhun wa, ibẹ ni wọn ti n wa gbogbo ọna lati tuṣu ọrọ yii desalẹ ikoko, tori awọn iroyin tawọn n gbọ fihan pe afaimọ ni ki i ṣe pe awo kan wa nidii bi wọn ṣe ṣeku pa Ọgbẹni Ataga, wọn ni boya ni ko jẹ awọn kan ni wọn lo Chidinma, tori o jọ pe iromi to n jo lori omi lọrọ ọhun, onilu ẹ wa nisalẹ odo.
Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, nileeṣẹ ọlọpaa ṣafihan afurasi ọdaran naa, Chidinma, to wa nipele kẹta ẹkọ nipa imọ ibanisọrọ kari aye (Mass Communication) ni UNILAG, l’Ekoo, nibẹ ni Odumosu ti ṣalaye pe aṣọ ti ẹjẹ ti rin gbingbin ni wọn lọmọbinrin naa wọ jade kuro ni otẹẹli to pa baale ile ọhun si lagbegbe Lẹkki, lo ba sa gba ọdọ awọn obi rẹ lọ ni Yaba, ibẹ si lawọn tọpasẹ rẹ lọ, ti wọn fi ri i mu.
Ọmọbinrin naa fẹnu ara rẹ ka boroboro fawọn oniroyin pe ko si irọ nibẹ, oun loun pa Oloogbe Ataga. O lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, niṣẹlẹ naa waye, o si sọ hulẹhulẹ boun ṣe gun un lọbẹ pa, ati idi toun fi ṣe bẹẹ.