Ọọdunrun simẹnti lawọn to n wa Maruwa yii ji tọwọ fi ba wọn nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

   Awọn ọkunrin mẹta yii, Lawal Bidemi, Ọlalekan Azeez ati Ọpẹloyẹru Kayọde ti wọn n wa kẹkẹ Marwa ti bọ sọwọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun bayii. Niṣe lawọn agbofinro ka wọn mọ’bi ti wọn ti n ko simẹnti sinu kẹkẹ ninu igbo kan ni Awa Ijẹbu, iyẹn lẹyin ti wọn ti ji ọọdunrun (300) simẹnti nile ikẹru-si ileeṣẹ simẹnti kan.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ onisimẹnti naa lo lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa ni teṣan Awa Ijẹbu, pe oun ri awọn kan ti wọn n ko simẹnti lapolapo sinu kẹkẹ Maruwa. Bẹẹ, ibi ti wọn ti n ko simẹnti yii ko jinna sileeṣẹ onisimẹnti toun ti n ṣiṣẹ.

Kia ni DPO teṣan naa, CSP Adewalẹyinmi Joshua, ti ko awọn eeyan rẹ lọ sibi ti wọn ni iṣẹ buruku naa ti n lọ lọwọ, wọn si ba awọn gende ti wọn n ko simẹnti si kẹkẹ loootọ.

Ṣugbọn bawọn onimaruwa naa ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si i sa lọ, awọn mẹta yii lọwọ ọlọpaa ba.

Nigba ti wọn mu wọn, awọn mẹtẹẹta jẹwọ pe ileeṣẹ simẹnti to wa nitosi lawọn ti ji awọn simẹnti ọhun, awọn  tọju ẹ sinu igbo ni. Wọn ni lati inu igbo naa lawọn ti n ko o lọ nipele ipele, tawọn si n ta a fawọn onibaara awọn ko too di pe awọn ọlọpaa de.

Apo simẹnti mọkanlelaaadọta (51) lawọn agbofinro ri gba lọwọ awọn eeyan naa, wọn si ri ogun (20) apo mi-in gba lọwọ ẹni kan ninu awọn ti wọn ta a fun. Awọn ọlọpaa ti gba kẹkẹ Maruwa ti wọn fi n ko ẹru ole naa wọgboro lọwọ wọn.

Ọjọ keji, oṣu kẹfa yii, lawọn ọlọpaa mu wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣe sọ. O ni ijọba faaye beeli silẹ fun wọn nigba naa, wọn si ni ti kootu ba ti bẹrẹ iṣẹ, awọn yoo ko wọn lọ si kootu.

Ṣugbọn niṣe lawọn ọdaran yii ko fẹẹ yọju si kootu mọ, wọn si bẹrẹ si i sọ ọ kiri pe DPO fẹẹ gbowo ẹyin lọwọ awọn ni, ati pe nigba tawọn ko fun un lowo naa lo ṣe gbẹsẹ le kẹkẹ tawọn fi n ṣiṣẹ.

Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa wa wọn de ibi ti wọn n fara pamọ si n’Ijẹbu-Ode, ibẹ ni wọn si ti tun wọn mu ni Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa.

Gbogbo awọn to sa lọ atawọn onibaara to ra ẹru ole naa lọwọ wọn ni ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti ni kawọn ọmọọṣẹ oun ri i daju pe wọn mu, o ni gbogbo wọn lo ni ijiya to tọ si wọn labẹ ofin.

Leave a Reply