Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Salaudeen Waliu, ti inagijẹ rẹ n jẹ Captain Walz, akẹkọọ ileewe giga Fasiti Ilọrin, to lu olukọ rẹ, Arabinrin Zakariyau, ti sọ pe idi ti oun fi lu u bii aṣọ ofi ni pe o ni koun waa lo ọdun kan si i nileewe tori ko ṣe SIWESI.
Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni Salaudeen ba awọn oniroyin inu ọgba fasiti naa sọrọ, o ni bii oṣu meji sẹyin, ko too di pe iṣẹlẹ naa waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, ni awọn ọlọpaa mu oun nipinlẹ Eko, lasiko ti oun n tọ, ti wọn si fẹsun ole jija kan oun, toun si lo oṣu meji gbeko ni atimọle ọlọpaa. Eyi lo ni o ṣokunfa idiwọ ti oun ko fi ri SIWESI to pọn dandan naa ṣe. Ṣugbọn nigba to ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun olukọ rẹ ti ko fi ri SIWESI ọhun ṣe, olukọ ni ko si iranlọwọ kan ti oun le ṣe, yoo pada wa lọdun to n bọ ni, eyi to tumọ si pe yoo lo ọdun kan si i nileewe, to si jẹ pe ipele aṣekagba lo wa.
Salaudeen tẹsiwaju pe ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, ti oun lọ si ọfiisi olukọ naa, ṣe lo le oun danu bii ẹran, ẹmi kan kan gun oun ni, inu si bi oun pẹlu, o ni bi oun ṣe bẹrẹ si i lu olukọ naa bii aṣọ ofi niyẹn. O lu obinrin naa lati ọfiisi rẹ titi, o lu u jade ninu ọfiisi, ko too di pe wọn gba olukọ naa silẹ, ti wọn si gbe oun lọ si tesan ọlọpaa F. Division, ni agbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin.