Akẹkọọ Poli Ọffa mẹrin fara pa ninu ijamba ọkọ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn, tawọn mi-in si fara pa ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọna Ọffa si Ojoku, ni Kwara.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ niṣẹlẹ ọhun waye laarin ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta tawọn eeyan mọ si Maruwa.

Awọn akẹkọọ Poli Ọffa la gbọ pe wọn fara pa ninu kẹkẹ Maruwa naa lẹyin ti wọn ni dẹrẹba ọkọ ayọkẹlẹ ọhun ti wọn pe ni mẹkaniiki to n sa ere asapajude lọọ rọ lu wọn.

Ibinu ohun to ṣẹlẹ sawọn akkọọ yii lo mu ki awọn ẹgbẹ wọn ya bo ọkọ Toyota Camry naa, ti wọn si dana sun un gburugburu.

Ọga agba ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Jonathan Ọwọade to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe wọn ti ko oku awọn eeyan naa si mọṣuari ileewosan gbogbogboo tilu Ọffa.

Ọwọade ni eeyan mẹjọ lo ni ijamba lasiko iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn mẹrin yooku ṣi wa nilewosan jẹnẹra, nibi ti wọn ti n gba itọju.

Leave a Reply