Akeredolu ṣe atunto ijọba rẹ, lo ba yọ kọmiṣanna kan bii ẹni yọ jiga

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lẹyin oṣu kan ataabọ ti wọn dibo yan an pada gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu ti ṣe atunto si igbimọ iṣakoso rẹ, bẹẹ lo si yọ kọmiṣanna kan bii ẹni yọ jiga.

Atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Sẹgun Ajiboye, fi sita laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, sọ pe Akeredolu ti yọ kọmisanna feto idajọ, Adekọla Ọlawọye, bii ẹni yọ jiga, to si ti fi Charles Titiloye rọpo rẹ lẹyẹ-o-ṣọka.

O dupẹ lọwọ kọmisanna ana ọhun fun isẹ ribiribi to ti ṣe laarin bii ọdun mẹta o le diẹ to ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu gomina, bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun sọna rẹ ni rere nibikibi to ba n lọ.

Ọkan ninu awọn gbajugbaja agbẹjọro to n ja fẹtọọ awọn eeyan ni Amofin Titiloye, bẹẹ lo ti figba kan jẹ akọwe fẹgbẹ awọn agbẹjọro ẹka tilu Akurẹ.

 

Leave a Reply