Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lori ipapoda Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Olubadan tilu Ibadan to waja lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un.
Gomina ọhun ninu atẹjade kan toun funra rẹ fi sita juwe iku Olubadan gẹgẹ bii adanu nla fawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, ilu Ibadan ati gbogbo Naijiria lapapọ.
O ni bo tilẹ jẹ pe Olubadan ti lọjọ lori daadaa ko too gori apere awọn baba nla rẹ, sibẹ, anfaani tijọba rẹ mu wa ki i ṣe fawọn eeyan ilu Ibadan to jọba le lori nikan, gbogbo eeyan ilẹ Yoruba patapata lo ni wọn jẹ anfaani ọba alaye ọhun laarin asiko to fi wa lori oye.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina lẹkun Guusu Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii ni adanu nla ni ipapoda Ọba Saliu jẹ lasiko yii tawọn eeyan ilẹ Yoruba si n ṣọfọ Ṣọun tilu Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Ọladunni Oyewumi lọwọ.
Aketi ni gẹgẹ bii ojulowo ọmọ Yoruba to nigbagbọ ninu aṣa ati iṣe wa, o ni oun mọ pe Olubadan ti lọọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ lẹyin to ti ṣiṣẹ takuntakun fun idagbasoke ilẹ Ibadan.
Ọba to ṣẹṣẹ gbesẹ naa lo ni o ti ṣe iwọn to le ṣe, ati pe awọn ogun rere to ti fi lelẹ ki i ṣe eyi tawọn eeyan le gbagbe bọrọ.