Ipo aarẹ ni 2023:Tinubu ni tabi Yẹmi Ọṣinbajo

Yẹmi Adedeji

Awọn eeyan kan n sọ kiri pe ko si ẹni ti Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo fi ẹnu ara rẹ sọ fun pe oun fẹẹ du ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria ninu eto idibo to n bọ ni ọdun 2023. Ẹni ti ko ba de ilu Abuja nikan ni yoo maa sọ bẹẹ, tabi ti ko mọ ohun to n lọ rara. Bii ọna mẹta ni patako agbesoke nla wa, eyi to si tobi ju ninu wọn wa ni ọna to lọ si papa-ọkọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, niluu naa, to jẹ pe ati ẹni to n lọ, ati ẹni to n bọ, lo n ri i, ohun ti wọn si kọ sibẹ ni “Jẹ ki iṣẹ naa tẹsiwaju, Yẹmi Ọṣinbajo nikan lo le ṣe e!” Yatọ si eleyii, ọpọlọpọ irin lo n lọ ni abẹlẹ, eyi to fi han gbangba pe Ọṣinbajo yoo du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023. Bẹẹ lawọn mi-in naa n sọ pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ko ti i fẹnu ara rẹ sọ pe oun fẹẹ du ipo aarẹ ni ọdun yii kan naa, ẹni ti ko ba le fi eeji kun ẹẹta nikan ni yoo sọ bẹẹ, nitori Tinubu ati awọn ọmọlẹyin rẹ ti fọnka sigboro, ohun ti wọn si n wa kiri ni awọn alatilẹyin ti yoo gbe e wọle.

Ki i ṣe pe Tinubu ṣẹṣẹ mọ pe oun yoo du ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023, bẹẹ ni ki i ṣe pe Ọṣinbajo naa ṣẹṣẹ mọ, onikaluku n duro de asiko ti ariwo ọrọ naa yoo ṣee pa sita ni, nitori laarin awọn mejeeji, boya Tinubu ni o, tabi Ọṣinbajo ni o, ẹni kan ṣoṣo naa lo le di awọn mejeeji lọwọ: Aarẹ Muhammadu Buhari ni. Ẹni yoowu ti Buhari ba fẹ ko di aarẹ, bo fi oju sọ ọ ni tabi o fi ẹnu sọ ọ, tabi ara nikan lo fi sọ ọ, tọhun ni yoo di aarẹ Naijiria ninu awọn mejeeji yii lọdun 2023. Ohun to han gbangba ṣaa ni pe nigba ti a ba fi eeji kun ẹẹta loootọ, tabi nigba ti ọrọ ba de oju ọgbagade, awọn meji ti yoo ṣe pataki ju lọ ninu idije ọdun to n bọ naa, Tinubu ati Ọṣinbajo ni o. Idi ni pe ko jọ rara pe Tinubu yoo fi ipo naa silẹ fẹnikan leyii to ti nawo, to ti nara, to si ti wa lọkan rẹ tipẹ, ohun to ba gba gan-an ni wọn yoo fun un.

Bẹẹ ni ko jọ pe Ọṣinbajo yoo fi ipo naa silẹ fun ọga rẹ atijọ, nitori nibi ti ọrọ naa ti de duro bayii, iṣẹ n lọ rẹpẹtẹ laarin awọn eeyan, nilẹ Hausa ati ilẹ Ibo, ko si si ohun meji ti iṣẹ naa da le lori ju pe Ọṣinbajo lawọn fẹ lọ. Ni ọsẹ to kọja yii ni ẹni ti ọpọ eeyan o ro pe awọn le gbọ iru ọrọ bẹẹ lẹnu rẹ jade si gbangba, ko si fi ọrọ naa si abẹ ahọn sọ rara to fi ni Ọṣinbajo loun fara mọ lati du ipo aarẹ ni Naijiria lọdun 2023. Ọrọ ti abiku ba sọ ni o, ara ọrun lo sọ ọ. lbrahim Babangida ki i ṣe ẹni kan ti i sọrọ pọnnbele ṣaa. Yatọ si pe ẹni to ti fi odidi ọdun mẹjọ ṣe ijọba orilẹ-ede yii, to ni ọrẹ nile, to ni ọrẹ loko ni, bii idaji ninu awọn agbaagba ilẹ Hausa lo maa n gbọ ọrọ si i lẹnu, ibi to ba ni ki wọn lọ ni wọn yoo lọ, amọran to ba si fun wọn ni wọn yoo tẹle. Eleyii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti wa bẹẹ lọjọ to pẹ. Bii arinu-rode lawọn mi-in mu ọkunrin Maradona naa.

Bi ọrọ oṣelu ba pa ilẹ Hausa ati awọn ẹya to ku ni Naijiria pọ, ẹnu Babangida lawọn aṣaaju yii maa n wo lati mọ ibi ti awọn yoo lọ. Nitori ẹ ni ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii ṣe jẹ nnkan iyanu, koda fun Tinubu ati awọn eeyan tirẹ, nitori awọn ko mọ pe ibi ti Ọṣinbajo yoo gba yọ si awọn niyẹn. Ṣe awọn naa ti kaakiri ilẹ Hausa, ṣugbọn wọn ko ti i ri ẹja nla kan gbe nibẹ, bi Ọṣinbajo ṣe wa to o, to jẹ Babangida loun gbe lodidi lẹẹkan naa yii ya wọn lẹnu pupọ, nitori ọkan lara awọn ti Aarẹ Muhammadu Buhari funra ẹ n gbọrọ si lẹnu ni Babangida i ṣe. Gbogbo wọn lo mọ ọn, wọn a si maa bẹru ọrọ to ba sọ. Bẹẹ ni ki i ṣe pe Babangida naa kan jade lo sọrọ yii, awọn kan ti wọn n ṣiṣẹ fun Ọṣinbajo ni wọn lọọ ba a, awọn ti wọn ba si ti mọ ọrọ oṣelu daadaa, wọn yoo mọ pe eto naa ko deede balẹ bẹẹ, awọn kan ni wọn to o, iṣẹ nla ni!

Idi ni pe ki i ṣe pe eeyan ti gbọ orukọ ẹgbẹ wọn yii tẹlẹ, bẹẹ ni ko si ti i si ninu iroyin pe wọn ti n lọ kaakiri. Ijade akọkọ ti wọn yoo jade naa ree, iyẹn awọn ẹgbẹ Ọṣinbajo Grassroot Organisation, ẹgbẹ mẹkunnu to fẹ ti Ọṣinbajo, ti Ojo Foluṣọ jẹ olori wọn. Ijade nla ni, ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn yii, Emma Ejiofor, lo ṣaaju wọn. Ọdọ Babangida ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ naa, ohun to si fi han ni pe o ṣee ṣe ki ọkunrin aloku-ṣọja naa ti mọ nipa eto yii tẹlẹ ni. Bi ko jẹ bẹẹ, ko ni i jẹ taarata ti ẹgbẹ naa n n lọ, ile Babangida ni wọn kọkọ gba, ti wọn lọọ sọ fun un pe awọn waa gba aṣẹ lẹnu rẹ, nitori Yẹmi Ọṣinbajo, igbakeji aarẹ Naijiria lọwọlọwọ bayii, n mura lati gba ipo naa lọwọ ọga rẹ bi tọhun ba ṣetan, ko si jẹ oun ni yoo maa ṣejọba naa lọ. Ọrọ ti Babangida gbọ niyi to gbe kinni ọhun ru, o si sọ ọ ju ibi ti awọn ọlọrọ paapaa sọ ọ de lọ.

“Ọṣinbajo ti ẹ ri yẹn, o fẹran Naijiria de gongo. Oun nikan lo le ba gbogbo ilu sọrọ ti wọn yoo tẹti si i, oun lo si le sọ fun wọn pe ki wọn ṣe bayii ti wọn yoo ṣe e, ọrọ ẹnu rẹ nikan si to lati ṣe atunṣe si ohun to ruju gbogbo! Bo ba jẹ ti idibo ọdun 2023 yii ni o, Ọṣinbajo lo dara ju lati ṣe aṣaaju Naijiria lọdun naa, oun lo yẹ ko ṣe olori wa.”  Babangida lo n sọ bẹẹ nigba ti awọn ẹgbẹ Ọṣinbajo Grassroot Organisation yii lọọ ba a ni ori oke tente to n gbe ni ilu Minna. Ọgagun agba naa ko ti i ṣetan o, o tun ni: “Mo mọ Igbakeji Aarẹ daadaa! Eeyan daadaa ni. Ẹni kan to nifẹẹ Naijiria, to si gbagbọ pe orilẹ-ede naa le ṣe aṣeyege ni. Ẹnikan to ṣe e wo niwaju ni o, ẹni ti ọrọ rẹ si le ye gbogbo eeyan ni. Iru eeyan bẹẹ yẹn lo ṣe e gbe ọpa aṣẹ le lọwọ pe ko ṣaaju wa, eeyan gidi la nilo bii aṣaaju ni Naijiria bayii, eeyan gidi si ni Ọṣinbajo.

“Orilẹ-ede Naijiria wa yii daa, awọn eeyan daadaa naa lo si wa nibẹ. Ki ẹni to ba jẹ olori kan mọ awọn eeyan rẹ daadaa ni, ọna to si fi le mọ wọn naa ni ko maa ba wọn sọrọ ni gbogbo igba. Mo fẹ ki ẹ ba mi sọ fun Igbakeji Aarẹ pe mo gbadura aṣeyege fun un, ẹ sọ fun un pe mo ni ko ma wo ọtun, ko ma wo osi, ibi to n lọ ni ko kọju mọ o. Mo mọ pe ki i ṣe nnkan to ma rọrun o, ṣugbọn mo gbadura fun un pe yoo ṣee ṣe!” Bẹẹ ni Babangida wi, to si n fi gbogbo ẹnu sọrọ pe ohun ti ọkunrin Igbakeji Aarẹ yii dawọ le yoo ṣee ṣe fun un. Gbogbo awọn ti wọn n tẹle Tinubu, ti wọn si ti ṣiṣẹ lọ bii ilẹ bii ẹni, ni kinni naa ko laya soke giri, nitori ojiji lo jẹ fun wọn, agaga nigba ti Babangida tun sọ fun awọn ti wọn lọọ ba a lorukọ Ọṣinbajo naa pe, oun mọ-ọn-mọ ri wọn nitori Oṣinbajo ni o. Eyi fihan pe tọwọ-tẹsẹ ni Babangida fi si ki Ọṣinbajo di aarẹ.

Tinubu naa ti jade silẹ Hausa, ṣugbọn ko ri iru ẹja nla bayii gbe, nitori awọn alatako laarin awọn eeyan naa pọ fun un. Lati fa oju awọn eeyan yii mọra, ọpọ awọn nnkan lo ti ṣe fun wọn, bi ki i ba si i ṣe pe awọn eeyan naa ya alaimoore, ko si idi ti wọn yoo fi ṣe atako Aṣiwaju. Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun to fẹẹ pari yii, wọn pe Tinubu sibi idanilẹkọọ kan ni Kaduna, idanilẹkọọ awọn Arewa ni, ipade nla si ni, nilẹ Hausa. Nigba ti Tinubu de ibi ti wọn ti ṣe ayẹyẹ naa, to jẹ yara-ikowee-si ati itọju ohun aṣa awọn Arewa, o ri i pe ibudo naa ko dara mọ, o ti n bajẹ lọ. Lẹsẹkẹsẹ ni Tinubu ni kinni naa ko tẹ oun lọrun, o ni oun yoo ko owo kalẹ, oun yoo si ri i pe wọn tun gbogbo ibẹ ṣe laarin oṣu mẹta pere. Bo tilẹ jẹ pe kinni naa jẹ owo nla, oṣu mẹta ti Tinubu wi ko yẹ, nitori wọn ko si yara tuntun naa ni ọjọ kẹtala, oṣu keje, 2021.

Bo tile jẹ pe Tinubu ko tete jẹwọ pe oun yoo ṣe oṣelu, ọrẹ rẹ to mu un lọ, Abdullahi Ganduje, Gomina ipinlẹ Kano ki i ṣe kekere. O ti lọ sibẹ laimoye igba, o si ti gbe owo nla kalẹ fun wọn, fun atunṣe mọṣalaasi gbogbogboo ilu naa, bẹẹ lo si ha owo rẹpẹtẹ fun awọn lemọọmu gbogbo nibẹ. Ọrẹ naa pọ debii pe ẹni kan jade ninu awọn aṣofin lati Kano yii pe Tinubu lawọn n ba lọ. O kan jẹ pe ọrọ naa da wahala silẹ ni, nitori ko pẹ lẹyin ọrọ ọhun ti ija buruku sọ ninu ẹgbẹ APC nibẹ, ti wọn si fọ ẹgbẹ naa si meji titi di bi a ti n wi yii. Ṣugbọn iyẹn ko da ọrẹ ti Tinubu ati Ganduje n ṣe duro, nitori Tinubu gboju le e pe ibo Kano lo pọ ju ni Naijiria, ẹni ti wọn ba si ti tẹle, yoo wọle bi ọrọ ba di ka dibo, boya ninu ẹgbẹ APC ni o tabi ninu idibo gbogbogboo. Lojoojumọ lawọn oloṣelu kan nibẹ tilẹ n ba iṣẹ lọ fun Aṣiwaju, wọn fẹ ko di aarẹ loootọ ni.

Ninu oṣu kọkanla to kọja yii ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Tanko Yakassai jade, baba arugbo loun, lara awọn oloṣelu atijọ si ni nibẹ. O ni Tinubu waa ba oun nile o, o si ti bẹ oun pe ki oun ṣe atilẹyin fun un. O ni awọn meji naa loun le ṣe atilẹyin fun ninu APC, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ, awọn eeyan mọ pe Ọṣinbajo ati Tinubu lo n sọ, ṣugbọn o ni oun ti pinnu pe ẹni to ba kọkọ waa ba oun ninu awọn mejeeji ni, nigba to si jẹ Tinubu lo kọkọ wa yii, Tinubu naa loun n ba lọ. Tinubu ko ti i fẹ ki ọrọ naa di ariwo nigba ti Yakassai ju bọmbu naa lulẹ, to si sọ fun gbogbo aye pe Tinubu fẹẹ du ipo aarẹ. Ni ọsẹ to kọja lọhun-un, ọkunrin Hausa kan naa jade, Mohammed Saleh loun n jẹ, o ni oun yoo ṣeto bi awọn ara Kaduna yoo ṣe tẹle Tinubu lasiko idibo to n bọ naa. O ni ki Jagaban ma daamu ara ẹ, awọn ti n ba iṣẹ lọ ni tawọn.

Eyi ni pe nibi ti ọrọ naa le si bayii, iṣẹ n lọ rẹbutu fun Tinubu nilẹ Hausa lọhun-un, nitori nibẹ ni ireti pọ si ju pe ẹnikẹni to ba fẹẹ du ipo aarẹ yii, to si fẹẹ wọle, o gbọdọ ri awọn oloṣelu ilẹ Hausa mu mọra. Ṣugbọn nnkan ko fi bẹẹ ṣe daadaa to ni awọn ibi ti Tinubu ni awọn eeyan si yii, nitori ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ ni Kaduna ti yoo jẹ nnkan idunnu fawọn Tinubu bi Nasir El-Rufai ba ṣi n ṣe gomina nibẹ. Ọkunrin naa koriira Tinubu, ko si fi bo. Ọpọ igba lo ti ta ko o ni gbangba, to ni ko lọọ jokoo, ko jẹ ki awọn ọmọde ṣejọba. Igba kan wa to ti pe awọn ara Eko pe ki wọn gba ipinlẹ naa kuro lọwọ Tinubu, nitori ko ro daadaa fun wọn, ati pe o n fi gbogbo ohun to n ṣe rẹ wọn jẹ ni. Nibi ipade awọn APC kan ni 2015, ni gẹrẹ ti wọn gbajọba, El-Rufai lo ṣaaju awọn ti wọn ni ko si ipo Aṣaaju APC apapọ ti Tinubu n pe ara ẹ ninu iwe ofin ẹgbẹ wọn.

Loootọ National Leader ni Tinubu n pe ara rẹ, bi wọn si ti pe e ko too di pe Buhari wọle niyi. Afi lojiji ti awọn oloṣelu ilẹ Hausa inu APC dide, ti wọn ni Tinubu ko le maa wa sipade awọn apaṣẹ ẹgbẹ naa, nitori ipo to n ru kiri yii ko si ninu ofin ẹgbẹ. Lati igba naa ni eegun Jagaban ko si ti ṣẹ mọ nibi ipade to ba ti jẹ ti awọn apaṣẹ ẹgbẹ APC. Bẹẹ ko too di igba naa, ọrẹ ni Tinubu ati awọn El-Rufai, ọrọ oṣelu pe Tinubu fẹẹ maa ṣe bii alagbara kan lẹgbẹẹ Buhari lo si pin wọn niya nigba naa. Titi di asiko yii, nnkan ko ṣe daadaa laarin wọn, ohun yoowu to ba si jẹ ti Tinubu, o daju pe ki i ṣe lẹgbẹẹ El-Rufai yii ni yoo ti ṣee ṣe. Bẹẹ ni ati Saleh ati Yakassai, ko si ẹni to sun mọ ile ijọba, tabi to mọ ohun to n lọ laarin awọn agbaagba ilẹ Hausa. Ọkunrin aṣofin kan, Shehu Sani, tilẹ ti ni ki Tinubu yee jẹ ki awọn oloṣelu ilẹ Hausa lu oun ni jibiti, o ni wọn n fi i jẹun lasan ni.

Loootọ lawọn kan n sọ laarin awọn Hausa yii pe Tinubu lo gbe Buhari wọle, ko si sohun to yẹ ko di awọn lọwọ lati ma ṣe ṣatilẹyin fun un pe ko di aarẹ. Ṣugbọn awọn ti wọn jẹ oloṣelu gidi laarin wọn ko gba, wọn ni ibo ti wọn ri lati adugbo naa ko to ihalẹ ati ariwo ti awọn oloṣelu ilẹ Yoruba n pa. Ni tiwọn, ko si ohun ti Tinubu ṣe ti awọn naa ko jẹ. Ọkunrin kan to tilẹ n mura lati di alaga ẹgbẹ APC bayii, Bunu Alli Modu Sheriff, lati ipinlẹ Borno, fẹẹ ba Tinubu ja ni gbangba lasiko kampeeni ti wọn n ṣe, o ni oun ko fẹẹ gbọ ki wọn pe ọkunrin naa ni Aṣaaju APC lapapọ, nitori kaluku ni aṣaaju ẹgbẹ naa ni adugbo tirẹ, aṣaaju APC loun ni ipinlẹ toun, bẹẹ si ni ko si ohun ti Tinubu ṣe fawọn eeyan rẹ ti oun naa ko ṣe fawọn eeyan oun paapaa nigba to jẹ asiko kan naa lawọn jọ ṣe gomina, ewo waa ni ki wọn maa pe Tinubu ni aṣaaju gbogbo awọn.

Bẹẹ Tinubu ati awọn eeyan rẹ ti ko oriṣiiriṣii ẹgbẹ jọ. Ọtọ ni awọn SWAGA, ọtọ ni awọn BAT, ọtọ ni wọn ABAF, ọto ni awọn tilu oyinbo, ọtọ ni awọn ti wọn n pe ara wọn ni Ẹgbẹ Ọmọlẹyin Jagaban, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ohun ti wọn si ṣe n sọ pe bi ọrọ ba de oju ẹ pata, Ọsinbajo ko lẹnu nibẹ niyi, ti wọn ni ko si ibi ti yoo ti rowo ti yoo na, bẹẹ ni ko ni agbara oṣelu tabi ọmọlẹyin ti yoo fi koju Tinubu, ẹni ti ṣe ọga rẹ. Awọn ti wọn n ṣiṣẹ fun Ọṣinbajo ni ọrọ ko ri bẹẹ rara. Wọn ni ẹni to ba fi oju ọgbara lasan wo Kudẹti, oluwa rẹ yoo b’odo lọ ni o. Ohun ti awọn yii n sọ ni pe ko si agba gidi kan nilẹ Hausa ti ko si lẹyin Ọṣinbajo, ohun ti wọn si ṣe fẹran rẹ ni pe wọn ni ni gbogbo igba to fi n ba Buhari ṣiṣẹ, ko gbo o lẹnu, tabi ko dalẹ rẹ nibi kan, pe ohun yoowu to ba ṣẹlẹ, ẹyin Buhari ni Ọṣinbajo n wa nigba gbogbo. Ohun to sọ ọ di ọrẹ awọn oloṣelu ilẹ Hausa niyi.

Wọn ni iṣẹ ti wọn n ṣe yii, ọpọlọpọ awọn gomina awọn lo wa lẹyin wọn, ti wọn si ti n ṣiṣẹ lọ labẹlẹ fun Ọṣinbajo, ko si jọ pe ẹnikẹni yoo ta ko o nibi kan. Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti sọ nigba to tipẹ sẹyin pe bi Ọṣinbajo ba ti le jade pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, ati oun ati Kayọde Fayẹmi ti Ekiti ni, ko si ẹni ti yoo tun jade ninu awọn mọ, awọn yoo si ṣe gbogbo atilẹyin ti awọn ba ni fun un ni. Bi ọrọ ba si ri bẹẹ, a jẹ pe laarin awọn meji yii naa ni ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ APC ṣee ṣe ko ja mọ lọwọ, nitori bo tilẹ jẹ awọn oloṣelu ilẹ Ibo naa yoo jade, ikoriira to wa nilẹ bayii laarin awọn eeyan naa ati awọn oloṣelu ilẹ Hausa, paapaa nitori awọn ti wọn n ja fun Biafra, ko ni i jẹ ki awọn to n ṣejọba yii fẹẹ gbe e fun ọmọ Ibo kankan. Ẹni to wa fẹẹ gba ipo naa laarin Tinubu pẹlu Ọṣinbajo ni ko si ẹni to ti i le sọ pato bayii, ṣugbọn ohun to daju ni pe ẹni yoowu ti Buhari ba tọka si, tabi to ba ti lẹyin laarin wọn ni yoo di aarẹ wa ni 2023.

 

Leave a Reply