Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ti fesi si ẹlẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai, ajaabalẹ lesi ọhun, o ni ọrọ ti El-Rufai sọ lori ipinnu awọn gomina ipinlẹ Guusu lati fofin de fifẹranjẹko ni gbangba lawọn ipinlẹ wọn pe ofin ti ko le ṣiṣẹ ni wọn n ṣe, ifakokoṣofo si ni awọn aṣofin to ti ṣofin ọhun, Akeredolu ni reluwee to ti lọ ni El-Rufai n ṣẹwọ si, ofin to ka ifẹranjẹko ni gbangba leewọ maa fẹsẹ rinlẹ ṣinṣin ni gbogbo agbegbe Guusu.
Akeredolu ni ọrọ ti ẹlẹgbẹ oun sọ yii lọwọ kan abosi ninu, o ni niṣe lọrọ naa da bii pe Gomina El-Rufai fẹ kawọn janduku agbebọn maa ti ilu odikeji wọ agbegbe Guusu lati bẹrẹ iṣẹẹbi wọn nibẹ, ko si le saaye fun iru nnkan bẹẹ, o lawọn o ni i gba iru ẹ lae.
Akeredolu fi esi ọrọ naa ran Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ rẹ, Ọgbẹni Donald Ọjọgọ, ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Gomina naa ni ẹnikẹni to ba sọ iru ọrọ ti wọn ni El-Rufai sọ yii, o ni lati jẹ pe tọhun wa lara awọn alaidaa ẹda ti wọn fi da awọn boju bii eegun pe ara wọn ni aṣaaju ni.
O ni ko si ọgbọn eleepinni ninu bibẹnu atẹ lu ofin to de ifẹranjẹko ni gbangba, ko si si laakaye ninu gigbẹsẹ le iru ofin bẹẹ, tabi ofin to ta ko kiko maaluu kiri lati ẹnubode Ariwa, to fi mọ Kaduna, wọ orileede tabi ilu mi-in ti wọn o ti nifẹẹ siru aṣa bẹẹ.
Atẹjade naa ka pe “Mi o ro pe o pọ ju ti mo ba sọ pe awọn eeyan bii Gomina El-Rufai yii wa lara awọn ti ojora ti n mu, ti wọn si n wa bawọn janduku agbebọn ṣe maa fi ọdọ wọn silẹ lọ sibomi-in, paapaa niru asiko yii tawọn ologun n da sẹria iku fawọn ọdaran afẹmiṣofo ti wọn ti gbọrẹgẹjigẹ lagbegbe Oke-Ọya yii.
Mo fẹẹ tẹnu mọ ọn pe to ba jẹ loootọ ni gomina ipinlẹ Kaduna sọrọ ti wọn lo sọ yii, a jẹ pe idarudapọ ati yanpọnyanrin lọkunrin naa n kọwe si pẹlu bo ṣe loun o nifẹẹ sofin tawa tọrọ kan ṣepinnu le lori yii.
Lọrọ mi-in, aboyun ọrọ ni, niṣe ni wọn fẹ ki iru aburu to n ṣẹlẹ lọwọ lapa Oke-Ọya, ti gbogbo afẹdafẹre ẹda n taka ẹ danu yii ṣẹlẹ ni iha Guusu. Ọgbọnkọgbọn buruku ni wọn n da yẹn.
Ẹ jẹ ki n sọ ni gbangba bayii, yẹkinni kan ko le yẹ ofin ma fẹran jẹko, paapaa nipinlẹ Ondo o. Gbogbo ohun to ba gba la maa fun un, tọkan-tara la maa fi daabo bo awọn araalu ipinlẹ Ondo, lai ka ẹya tabi ẹsin kaluku si. Ẹni ti ko ba ṣe nnkan itufu ko ni lati maa ṣọ ẹyinkule, ẹni ba lẹbọ lẹru lo le maa bẹru ofin.” Bẹẹ ni Akeredolu pari ọrọ rẹ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, bu ẹnu atẹ lu bawọn gomina ipinlẹ agbegbe Guusu kan ṣe n bọwọ lu ofin to ka fifẹran jẹko leewọ lawọn ipinlẹ kaluku wọn.
El-Rufai ni ofin ti wọn n gbe kalẹ naa ki i ṣe ofin gidi kan, ofin oloṣelu ni, ọrọ oṣelu ni wọn n fi ṣe, ati pe ofin naa ko le mulẹ rara tori ki i ṣe ofin to le ṣiṣẹ lorileede yii.
Olu-ile ẹgbẹ APC l’Abuja ni El-Rufai ti sọrọ naa nigba to n dahun ibeere awọn oniroyin lori ọrọ ọhun, o ni ki i ṣe pe oun ko fara mọ kawọn darandaran wa lojukan, ki wọn kọ ibi ijẹko fun wọn, ṣugbọn iru nnkan bẹẹ maa n gba akoko, ki i ṣe nnkan tijọba maa dide wuya, ti wọn yoo si pari laarin akoko perete, tori bẹẹ ko yẹ kawọn gomina kan fofin de ifẹranjẹko lọsan-an kan oru kan.
El-Rufai ni: “Ko ṣanfaani bawọn ṣe n ki ọrọ oṣelu bọ’rọ yii, pẹlu bi wọn ṣe n gbe ofin tawọn funra wọn mọ daadaa pe ko le ṣiṣẹ, kalẹ. Awa gomina apa Oke-Ọya ti forikori lọri ọrọ yii, a si ti ṣe ipinnu lori ẹ.
Agbegbe ọdọ wa lawọn darandaran ti n jade lọ, a si ti pinnu lati jẹ ki wọn wa loju kan, ṣugbọn ki i ṣe nnkan ta a le ṣe loru mọju. A nilo owo, obitibiti biliọnu naira lo maa na wa. Ibudo ifẹranjẹko kan ṣoṣo pere ni mo n kọ lọwọ nipinlẹ Kaduna to ti n na wa to biliọnu mẹwaa naira yii, bẹẹ iru ẹ bii mẹrinla la ni lati kọ ni kaakiri ipinlẹ Kaduna, ṣe mo ni biliọnu mẹwaa naira lọna mẹrinla lọwọ, abi ẹ mo iye ti iyẹn jẹ ni? Mi o lowo to to bẹẹ?
“A fẹẹ yanju iṣoro ni, ki i ṣe pe a fẹẹ da kun un. Mo si lero pe awọn Fulani darandaran maa gba pe ọna to daa ju leyi ti a n ṣiṣẹ le lori yii, dipo ti wọn aa maa da ẹran kiri inu igbo, ti wọn aa maa lọ maa fi maaluu jẹ ire-oko oloko, tabi ti wahala mi-in aa maa ṣẹlẹ. Ọrọ to gba suuru ati asiko ni o.”