Akeredolu kọ lu Sunday Igboho, o ni ko ma gbe wahala orilẹ-ede Oodua de Ondo

Jide Alabi

Gomina ipinlẹ Ondo, Amofin-agba Rotimi Akeredolu, ti sọ pe ipinlẹ Ondo ko ṣetan lati ya kuro lara Naijiria, ati pe Oloye Sunday Igboho kọ ni yoo sọ ohun ti iran Yoruba n fẹ lasiko yii.

Niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni Akeredolu ti sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lasiko to n ṣebura fun akọwe ijọba tuntun to ṣẹṣẹ yan, Ọladunni Odu, atawọn mi-in ti wọn yoo ba ijọba ẹ ṣiṣẹ.

Ṣaaju asiko yii ni Sunday Igboho, ti sọ pe awọn ẹya Yoruba ti wọn wa ni Naijria ti ṣetan bayii lati da duro gẹgẹ bii orilẹ-ede. Nibi apejọ kan to waye lọsẹ to kọja, nibi ti Ọjọgbọn Banji Akintoye, ẹni ti i ṣe alaga ọkan lara awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti wa nikalẹ lo ti sọrọ ọhun.

Igboho sọ pe, “Lati isinyii lọ, a ko fẹ awọn darandaran mọ nilẹ Yoruba, awọn Fulani ti wọn n fi maaluu jẹ oko, ti wọn n ko awọn agbẹ si wahala nilẹ Yoruba, a ko fẹẹ ri wọ mọ. Lọjọ ti a ba foju kan Fulani agbebọnrin, niṣe la oo doju ija kọ ọ. Ti a ba waa ri ọlọpaa to tori ẹ kọ lu wa, awa naa ṣetan lati ba wọn fa a daadaa. Ni tiwa o, awa ko fẹ orilẹ-ede Naijiria mọ, orilẹ-ede Oduduwa gan-an lohun ti a n beere fun lasiko yii.

“Kin ni lajori Naijiria ti a wa, nibi ti gbogbo ere ti a n ri pata lori awọn ohun alumọọni orilẹ-ede yii ti n bọ sọwọ awọn Hausa l’Oke-Ọya lọhun-un. O to gẹẹ o, ko si ohun meji ta a fẹ, Yoruba ṣetan lati ṣe tiẹ lọtọ ni.”

Ọrọ yii ni Sunday Igboho sọ o, lọjọ Aje, Mọnde, si ni Akeredolu fun un lesi ẹ pe ipinlẹ Ondo ko ni i si ninu ilẹ Yoruba to n sọ pe o fẹẹ kuro lara Naijiria. O loun atawọn eeyan oun ko ni ibi tawọn n lọ ni tawọn, ara Naijiria yii lawọn fẹẹ wa.

“Pẹlu bi nnkan ṣe n ṣẹlẹ lasiko yii, gbogbo wa naa la mọ pe ilu ko fara rọ. Kaluku naa lo n sọ bi ọrọ ọhun ṣe dun un to, ṣugbọn nibi tawọn kan ti n fi agbekalẹ to dara sọrọ wọn, nibẹ naa la ti ri awọn mi-in to jẹ pe bo ti ṣe n ka wọn lara si ni wọn fi n sọ ọ, ibeere ti mo fẹẹ bi awọn kan ti wọn n sọ pe ohun ti Yoruba fẹ ree ni pe ta lo fi iru iṣẹ bẹẹ ran wọn. Ki ẹnikẹni too le sọrọ loruko iran Yoruba, o gbọdọ jẹ pe gbogbo wa la sọ pe ohun ta a fẹ ree. Iru ọrọ ti wọn n gbe kiri nipa pe Yoruba fẹẹ kuro ninu Naijiria, ta lo fun wọn niru aṣẹ bẹẹ.

“Gbogbo eeyan naa lo lẹtọọ lati sọrọ, bẹẹ ni wọn lẹtọọ lati jijagbara pẹlu, ṣugbọn ohun gbogbo lo yẹ ko ni odinwọn. Ki a too le sọ pe ohun bayii la n fẹ, ohun ti gbogbo wa gbọdọ jọ fọwọ si ni. Mo fẹẹ sọ ọ lasọye pe ipinlẹ Ondo ko lọwọ si ariwo ti awọn eeyan kan n pa kiri pe Yoruba yoo kuro lara Naijiria, awa ko lọ sibi kankan ni tiwa, ọmọ Naijiria rere ni wa, ara Naijiria la ṣi wa ni tiwa.

“Loootọ lawọn kudiẹ kudiẹ kọọkan wa, ṣugbọn asọyepọ lo ṣe pataki, ki i ṣe ilu bo le dogun ko dogun ti awọn eeyan kan n lu kiri. Nipinlẹ Ondo, awa ko fọwọ si ijinigbe atawọn iwa buruku mi-in to le maa di alaafia orilẹ-ede lọwọ, ṣugbọn asọyepọ lo ṣe pataki lasiko yii, ki i ṣe ariwo ogun ti awọn kan n pa kiri. Ipinlẹ Ondo ko ran Igboho niṣẹ lati sọrọ fun wa, a mọ ohun ta a fẹ nibi, bẹẹ la o ṣetan lati kuro lara Naijiria.”

Leave a Reply