Akeredolu lo n lewaju, Ajayi ti gba kamu, lo ba n dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Bo tilẹ jẹ pe ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii ko ti i kede ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, sibẹ, Igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, ti dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ fun aduroti wọn latẹyinwa.

Oludije ẹgbẹ Zenith Labour Party ọhun ninu atẹjade to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Allen Soworẹ, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni tọkantọkan loun fi n dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ, Ọnarebu Joseph Akinlaja to jẹ alaga wọn nipinlẹ Ondo ati Dokita Olusẹgun Mimiko fun akitiyan wọn saaju ati lẹyin eto idibo naa.

Ajayi ni asiko ọrọ ko ti i to, o ni o digba toun bá gbọ abọ bi eto idibo ọhun ṣe lọ lati ẹnu awọn aṣoju ẹgbẹ ti awọn ran jade ki oun too mọ igbesẹ to kan lori abajade eto idibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu ZLP nikan ni ko rọwọ mu, bẹẹ ni ko si ibi ti oludije rẹ tí yege ninu awọn ijọba ibilẹ mẹẹẹdogun tí wọn ti kede abajade idibo wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: