Akintọla ni Ẹgbẹ Dẹmọ lo ni West, ṣugbọn awọn alatako rẹ ni baba-nla irọ ni

Nigba ti wahala awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group, ẹgbẹ Ọlọpẹ, ti i ṣe ti Ọbafẹmi Awolọwọ ati awọn ọmọlẹyin rẹ fẹẹ pọ ju, awọn ẹgbẹ Dẹmọ, labẹ alaṣẹ tiwọn naa ti i ṣe Ladoke Akintọla jẹwọ pe awọn ki i ṣe ojo, ati pe ko si ohun to n bọ loke ti ilẹ ko gba, agunfọn lawọn, awọn ko ni i fori balẹ fẹni kan. Ẹgbẹ naa jade lati sọrọ, ọrọ ti wọn si sọ ko girigiri ba awọn ẹgbẹ Ọlọpẹ, ati awọn alatako Akintọla to ku, nitori wọn ko tete mọ ohun ti wọn yoo sọ si i. Olori ẹgbẹ naa funra rẹ, iyẹn Akintọla, lo jade to sọrọ, ohun to si sọ ni pe ọna ti ẹgbẹ Demọ gba ti wọn fi wọle ibo ti wọn di loṣu kejila, ọdun 1964, ọna yii kan naa ni wọn yoo gba ti wọn yoo fi wọle ninu ibo yoowu ti wọn ba di ni Western Region ni 1965. Ọkunrin olori ijọba naa ni ohun meji ni yoo jẹ ki eleyii ṣee ṣe, akọkọ ni pe Ọlọrun wa lẹyin awọn, ẹẹkeji si ni pe gbogbo awọn ọmọ Yoruba ni Western Region ati nibikibi ni wọn wa lẹyin awọn.

Akintọla sọ bayii ninu atẹjade rẹ pe, “Awọn ti wọn dibo fun ẹgbẹ Dẹmọ ninu ibo ijọba apapọ ta a di kọja lọ yii, awọn naa ni yoo tun dibo fun ẹgbẹ yii lati ri i pe awọn ni wọn wọle ninu ibo yoowu ta a fẹẹ di, ati ni ọjọ yoowu ti a ba fẹẹ di i ni 1965, ki awọn Action Group yee da ara awọn ninu dun lasan, tabi ki wọn ro pe awọn ni idan kan ti awọn fẹẹ pa bi ibo naa ba de!” Olori ẹgbẹ Dẹmọ yii ni bi ọmọde ba kọ iyan ana lọrọ to wa nilẹ yii o, awọn agba yoo fi itan balẹ ni, wọn ni ibo ti awọn di lasiko yii ti fihan pe ẹgbẹ Dẹmọ lero lẹyin ju ẹgbẹ Ọlọpẹ lọ, nitori ibo ti awọn di lọdun naa dara pupọ ju eyi ti awọn ti n di sẹyin lọ. Wọn ni nigba ti wọn ba wo iye ibo ti wọn di ni ọdun naa fun ẹgbẹ Dẹmọ, wọn yoo ri i pe o ju eyi ti awọn eeyan di fun ẹgbẹ Ọlọpẹ ni 1959 lọ, eyi ti fihan pe gbogbo Yoruba bayii, ti Dẹmọ ni wọn n ṣe.

Atẹjade Akintọla yii ṣalaye pe lati bii ọdun mẹrin ṣẹyin, o fẹrẹ ma si ọdun kan ti awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin, ati tawọn igbimọ awọn ọba ko jade lati sọ pe awọn ni igbagbọ ati igbẹkẹle to peye ninu ijọba oun Akintọla, ti wọn si n fi han pe awọn fara mọ ọn bi oun Akintọla ti n ṣe olori wọn. O waa beere pe ni gbogbo ọdun ti Awolọwọ fi ṣejọba tirẹ, igba wo ni awọn kan jade ti wọn ni awọn ni igbẹkẹle ninu ijọba AG tabi ti Awolọwọ funra rẹ, ṣebi wọn kan n fara mọ ohun ti ẹgbẹ naa ba ṣe ni, nigba ti ko sẹni to le sọrọ ninu wọn. Ṣugbọn ni bayii, Akintọla ni gbogbo eeyan lo n fẹran ijọba tawọn, nigba to jẹ gbogbo ohun ti awọn n ṣe lawọn n fi han wọn, ti wọn si mọ pe tiwọn ni ẹgbẹ Dẹmọ awọn n ṣe lọjọ gbogbo. O ni ninu Ọlọrun lawọn ni igbẹkẹle awọn o, ọkan awọn si balẹ pe awọn eeyan awọn kankan ko ni i ja awọn kulẹ.

O ni kinni kan loun fẹ ki gbogbo eeyan mọ, iyẹn naa ni pe ẹnu ti awọn AG n fọn kiri yii, ati ariwo ti wọn n pa, ko ni i jẹ ki wọn wọle ibo ni Western Region, nitori awọn eeyan ti gbọn, wọn si ti mọ pe ariwo lasan lo wa lẹnu wọn. O ni, “Ni 1964, Ọlọrun ati awọn araalu wa lẹyin wa, iyẹn naa la si fi wọle ibo, ti a na gbogbo awọn alatako wa ni anabami. Ninu ibo ti wọn tun n pariwo yii naa, lọjọkọjọ ti a ba di i, a oo tun na wọn ba a ti ṣe lọdun to kọja yii naa ni. Ki waa ni wọn n pariwo si. Ẹni to ba mọ wọn ko sọ fun wọn pe gbogbo ifọnnu ati giragira ti wọn n ṣe yii ko ni i jẹ ki wọn wọle ibo ẹyọ kan bayii ni Western Region, nitori ẹgbẹ Dẹmọ lo ni West”. Bẹẹ ni Akintọla wi, pẹlu ibalẹ-ọkan pe nigba ti ibo yoowu ba ti de ni West, awọn lawọn yoo jawe olubori, awọn AG, ẹgbẹ Ọlọpẹ, yoo kan maa woran lasan ni.

Ọrọ naa bi awọn ẹgbẹ Ọlọpẹ ninu gan-an, o si dun wọn pe Akintọla yoo lanu sọ iru ọrọ bẹẹ sawọn. Ṣugbọn awọn kọ ni wọn yoo da esi ọrọ pada fun Akintọla, awọn UPGA, ẹgbẹ alajọṣepọ ti NCNC ati AG jọ ṣe ni. Awọn ni ki Akintọla dakẹ ni, wọn ni ailojuti lo fa a to n sọ pe ibo ti awọn di ni 1964 pọ ju eyi ti wọn di ni 1959 lọ. Wọn ni ṣe o ti gbagbe pe ni 1959 to n sọ yii, awọn ondibo miliọnu kan ati ọọdunrun (1.3 million) ni wọn dibo nigba naa, bẹẹ ni 1964 to n wi yii, awọn eeyan ti ko pe miliọnu kan ati irinwo (1.4 million), ni wọn dibo, eyi ti awọn ti wọn dibo ni 1964 fi le ni pe awọn ti wọn dibo ni 1959 ko ju ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) lọ. Wọn ni ki oun naa ro o lọkan ara rẹ, ṣe ko yẹ ki awọn ti wọn fẹẹ dibo maa le si i ni abi ki wọn maa pọ si i, nigba to ṣe pe lojoojumọ ni iye awọn ero to wa ni ilu kọọkan n pọ si i.

UPGA ni awọn tilẹ ti tun waa woye pe ninu awọn ẹni mẹwaa ti wọn ba dibo ni West ni 1959, awọn mẹjọ ni yoo dibo fun ẹgbẹ AG, ko jọ ti asiko yii to jẹ nigba ti wọn dibo wọn tan, awọn bii ẹni mẹrin pere lo dibo fun ẹgbẹ Dẹmọ ninu awọn mẹwaa to ba dibo, sibẹ, wọn fi eru gbe ara wọn wọle, wọn waa n sọ pe awọn eeyan wa lẹyin awọn. Ẹgbẹ yii ni ko sẹni ti ko mọ pe onijibiti ati oniwayo lẹgbẹ awọn Akintọla, pe awọn ara West mọ pe ẹgbẹ Dẹmọ ko ni alaafia kan to fẹẹ fun awọn, bẹẹ ni ko si mu ilọsiwaju wa, ohun ti wọn ṣe ni pe ki wọn tete ṣeto idibo mi-in ree, ki awọn le bọ lọwọ wọn. Wọn ni ki Akintọla ma rojọ mọ, ko sinmi alaye, ohun ti awọn eeyan n fẹ ko ṣe naa ni ko ṣe. Ko si si ohun meji ti wọn fẹ ko ṣe ju ko tu ile ka lọ, ko si dajọ ibo tuntun ni West, ki awọn eeyan naa le yan aṣaaju ti wọn ba fẹ.

Akintọla ti ri i pe ko si ogun mọ, ko si sọna ti awọn yoo gba, ki awọn tete maa mura lati ṣeto idibo naa ni. Ṣugbọn ki wọn too ṣe bẹẹ, wọn yoo fi ohun gbogbo si ipo rẹ, wọn yoo si ṣe atunṣe to ba yẹ. Kia ni wọn ti yan ọkunrin kan bayi gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin, oun lo si gba ipo lọwọ Adeleke Adedoyin to ti n ṣe olori ile igbimọ naa lati igba ti Akintọla ti gba ijọba rẹ tuntun. Ẹni ti wọn ṣẹṣẹ fi ṣe olori ile-igbimọ aṣofin yii ni Ọgbẹni Thomas Ẹgbẹlọla Elushade, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ lati Ile-Ifẹ ni. Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, 1965, ni wọn si yan an gẹgẹ bii olori ile-igbimọ naa. Ohun tawọn Akintọla si n ṣe ni lati ri i pe gbogbo ipo pataki daadaa bọ si ọwọ awọn ẹgbẹ Dẹmọ, ki wọn le duro lati ṣe eto gbogbo nigba ti ibo naa ba de, ko ma si pe ẹgbẹ kan yoo wa nibikan ti yoo ni awọn eeyan ti wọn lagbara lati da nnkan ru fawọn.

Yatọ si eyi, Akintọla yan Ayọ Rosiji gẹgẹ bii ọkan lara awọn ti wọn yoo lọ si ile-igbimọ aṣofin agba, ti wọn yoo lọọ ṣoju Western Region nibẹ. Awọn yii ni wọn n pe ni sẹnetọ, ṣugbọn yatọ si bi nnkan ṣe ri bayii, ki i ṣe pe wọn n dibo fun awọn sẹnetọ nigba yẹn, ijọba ipinlẹ wọn lo maa n yan wọn sipo naa. Rosiji fẹẹ lọ sile-igbimọ aṣofin apapọ ni, ṣe nibẹ lo wa lati ọjọ yii, orukọ ẹgbẹ AG lo si fi wọle, ko too di pe o papa di igbakeji olori ẹgbẹ Dẹmọ. Ṣugbọn nigba ti wọn dibo ni 1964, ọkunrin naa ja bọ ni Abẹokuta, nitori ikoriira awọn eeyan pọ fun un debii pe wọn ko tilẹ fẹẹ ri i. Nigba ti wọn dibo to ja bọ yii, Akintọla ko ri ohun meji ti yoo ṣe ju lati yan an lọ si ile-igbimọ aṣofin agba lọ. Awọn yii ko lagbara pupọ, bii oludamọran lasan ni wọn jẹ sijọba. Sibẹ naa, eleyii san fun Rosiji ju bi wọn ṣe fẹẹ fibo da a jokoo sile lọ.

Awọn eeyan binu si eyi naa, wọn ni bawo ni Akintọla yoo ṣe yan ẹni ti awọn eeyan fi ibo ja bọ pada si ile-igbimọ bii aṣoju wọn, nigba ti awọn araalu ti sọ pe awọn ko fẹ ẹ. Ṣugbọn Akintọla mọ ohun ti oun ṣe, ipalẹmọ ibo ọdun 1965 naa lo ti bẹrẹ yii, nitori ibo to fẹẹ fi gbogbo agbara to ni ati ọgbọn oṣelu to mọ, ja ni. Oun naa mọ pe bi oun ko ba wọle ibo naa, bi ijọba ba bọ lọwọ oun ni ti idibo 1965 yii, nnkan yoo bajẹ kọja atunṣe. Nitori bẹẹ, Akintọla ti mura pe ibo 1965 naa, gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un.

Ẹ tẹsiwaju ninu itan naa lọsẹ to n bọ.

 

Ileeṣẹ panapana doola eeyan meje lọwọ atẹgun ojo ni Kwara

 

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Eeyan meje ọtọọtọ lori ko yọ ninu ijamba ti atẹgun ojo to rọ mọju ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja. Ileeṣẹ panapana tipinlẹ Kwara lo doola ẹmi wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nidojukọ ileejọsin C & S, lagbegbe Muritala, niluu Ilọrin.

Lara wọn ni awọn baba agbalagba ti atẹgun ojo naa wo orule ile lu mọlẹ, atawọn ọdọ pẹlu ọmọde.

Alukoro ileeṣẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye pe ileewosan gbogbogboo to wa lagbegbe Surulere, niluu Ilọrin, lawọn ko awọn eeyan naa lọ lati gba itọju.

Awọn ibomi-in ti wọn tun ti ri awọn eeyan doola ni Ita-Igba ati Emirs Road, laarin igboro ilu Ilọrin.

O ni iṣẹ ọhun ṣee ṣe pẹlu atilẹyin Kọmiṣanna fun iṣẹ ode ati irinna ọkọ, Alhaji Suleiman Iliasu, ẹni to kopa ribiribi lati ri i pe wọn ri awọn eeyan ọhun tọju nileewosan.

Ọga agba ileeṣẹ panapana, Alh. Waheed I. Yakub, gba araalu nimọran lati maa ṣọra, ki wọn si maa wa ibi to dara duro si lasiko ti atẹgun ojo ba n fẹ, ati bi ojo nla ba n rọ.

Leave a Reply