Aderounmu Kazeem
Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ, Rẹfurẹndi Tọla Oyediran, ti ku o.
Oni, Fraide, ọjọ Ẹti, ni oloogbe yii jade laye lẹni ọdun mọkandinlọgọrin. Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe, ọjọ kin-in-ni oṣu kejila ọdun yii gan an ni iya agbalagba yii, ẹni ti ṣe akọbi Awolọwọ iba pe ẹni ọgọrin ọdun laye.
Titi di asiko to fi jade laye, wọn ni Mama naa ni Alaga fun awọn oludari African Newspapers of Nigeria, iyen ileeṣẹ to n tẹ iwe iroyin Tribune.
Ṣaaju ki ọlọjọ too de, wọn ni obinrin Ojiṣẹ Ọlọrun yii ko ṣaisan kankan, paapaa ni gbogbo alẹ ana ko too dagbere faye wi pe o digbooṣe.