Aderounmu Kazeem
Tọsidee, Ọjọbọ ọsẹ to n bọ yii lawọn eeyan yoo ko sinu aṣọ nla, ti gbogbo ọmọ Yoruba nibikibi ti wọn ba wa yoo panupọ ṣadura fun Ọba Lamidi Atanda Adeyẹmi, Alaafin Ọyọ bi yoo ti ṣe pe ẹni ọdun mejilelọgọrin loke eepẹ.
Nibi ọjọọbi ẹ yii, kakiiri lawọn eeyan yoo ti wa, nitori o jọ pe, Ikubaba yeye fẹẹ fa ayẹyẹ ọhun gan-an ni.
Kaakiri lawọn eeyan ti n palẹmọ ayẹyẹ nla yii, ohun tawọn eeyan si n sọ ni pe, lọdọ Atanda Lamidi, Alaafin ̀Ọyọ, ọjọ gbogbo bii ọdun ni, ti imura fun ọjọọbi ọhun si n lọ gidigidi.
ALAROYE gbọ pe lọdun to kọja, ọna ara ni kabiyesi yii gba ṣe e, kaakiri si lawọn ọba Yoruba ti waa baa ṣajọyọ, ti awọn ile ijọsin loriiṣiiriṣi paapaa ṣeto isin manigbagbe fun Alaafin.
Lẹẹkan si i, awọn oniṣẹkẹrẹ yoo tun ri iṣẹ nla ṣe, nibi ti wọn yoo ti dabira nla fun Ọba Adeyẹmi, ti Ikubabayeye yoo si jo si ṣẹkẹrẹ gẹgẹ bii iṣe rẹ, ti ẹbun lọlọkan-o-jọkan yoo si maa pe ara wọn ranṣẹ pẹlu, nitori Alaafin naa ni.