Faith Adebọla, Eko
Lẹyin ti Kọmiṣanna ọlọpaa Eko telẹ, Hakeem Odumosu ti gba igbega si ipo igbakeji ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, to si ti di dandan fun un lati pada si ilu Abuja lati maa ba iṣẹ rẹ lọ, Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa apapọ ilẹ wa, IGP Usman Alkali Baba, ti buwọ lu iyansipo Ọgbẹni Alabi Abiọdun Sylvester, gẹgẹ bii Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun fun ipinlẹ Eko.
Iyansipo naa waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, l’Abuja, wọn si ti paṣẹ ki kọmiṣanna naa bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ.
Ninu atẹjade kan lati ileeṣẹ ọlọpaa apapọ, eyi ti Alukoro wọn, Frank Mba, fi lede, o ni Alabi ni yoo gbaṣẹ lọwọ AIG Hakeem Odumosu to ti wa nipo kọmiṣanna Eko lati ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 2019, ipari ọdun to kọja yii lo si gba igbega si ipo igbakeji ọga agba patapata, Assistant Inspector General.
Ṣaaju iyansipo rẹ, Kọmiṣanna Abiọdun Alabi ti figba kan jẹ igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Taraba Bayelsa ati Ekiti, bẹẹ lo ti jẹ ọga agba ọpọlọpọ ẹka iṣẹ agbofinro ati ọtẹlẹmuyẹ nileeṣẹ ọlọpaa. Ọdun 1990 lo wọṣẹ ọlọpaa, ni ipele Cadet.
Bakan naa ni kọmiṣanna tuntun yii kawe, o gboye jade ninu imọ ajọṣepọ ẹda eeyan (sociology) ni fasiti Eko (University of Lagos), o si gba to ga, Masita, ni Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, eyi to wa n’Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun.