Alaga APC, Adamu, ni Ahmed Lawan lẹgbẹ awọn fa kalẹ funpo aarẹ

Faith Adebọla
Awuyewuye mi-in ti su yọ laarin ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) l’Abuja, pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ bẹrẹ eto idibo abẹle wọn lati yan ẹni ti yoo jade dupo aarẹ, Alaga ẹgbẹ naa, Abdullahi Adamu, ti kede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa yii, pe Sẹnetọ Ahmed Lawan, olori awọn aṣofin apapọ, ni ẹni ti ẹgbẹ APC fẹnuko le lori lati fa kalẹ.
Lasiko to n ṣepade pẹlu igbimọ amuṣẹṣe, National Working Committee, ẹgbẹ naa, eyi to waye lolu-ile ẹgbẹ APC l’Abuja lo sọrọ naa.
Ṣugbọn o ni awọn maa gba awọn oludije yooku, titi kan adari apapọ ẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Gomina Ekiti, Kayọde Fayẹmi, Gomina Ebonyi, David Umahi, ati awọn yooku laaye lati dije pẹlu Ahmed Lawan, lasiko ti eto idibo naa ba bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Papa iṣere Eagle Square, l’Abuja ni eto idibo naa yoo ti waye.

Leave a Reply