Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, ti sọ pe ọrọ kan ti Minisita fun ọrọ abẹle, to tun jẹ gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, sọ niluu Ileṣa lọjọ Ẹti, Furaidee, osẹ to pari yii pe ẹgbẹ oṣelu APC ti pin si meji l’Ọṣun, ati pe igun TOP loun wa, tabuku oju adari ti awọn fi n wo o.
Ninu atẹjade kan ti Famọdun fọwọ si lo ti ni ọrọ to jade lẹnu minisita naa ki i ṣe eyi to yẹ ki wọn maa gbọ lẹnu ẹni to larojinlẹ lawujọ.
Famọdun ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ pe Arẹgbẹṣọla, ẹni to jẹ gomina ana nipinlẹ Ọṣun, le sọ ara rẹ di adari agbesunmọmi ta ko ẹgbẹ oṣelu to sọ ọ di kọmiṣanna nipinlẹ Eko, gomina fọdun mẹjọ nipinlẹ Ọṣun ati minisita to n ṣe lọwọlọwọ.
O ni ki Arẹgbẹṣọla gbagbe erongba rẹ lati di alfa ati omega osẹlu ipinlẹ Ọṣun, ati pe ṣe lo n yan fanda ninu ogo to ti ṣi kuro lọdọ rẹ.
Famọdun sọ siwaju pe ẹgbẹ oṣelu APC lagbara ju eyi ti Arẹgbẹṣọla le fọ si wẹẹwẹ lọ. O ni “Onigberaga, onimọ tara ẹni nikan, ika, oninakunaa ati ẹni ti ki i ro ti ọmọnikeji ni Arẹgbẹṣọla.
“Ki i ṣe ọrọ asọju ti eeyan ba sọ pe Arẹgbẹṣọla jẹ ẹnikan to gbagbọ ninu jijẹ adari ninu ọrun-apaadi ju ọrun rere lọ.
“Ẹ ba mi sọ fun Arẹgbẹṣọla pe ko si iye rikisi to le ṣe tabi ọgbọn alumọkọrọyin to le lo to le da saa keji Gomina Oyetọla duro rara nitori o ti wa ninu akọsilẹ aṣẹdaa Oyetọla pe yoo ṣe gomina Ọṣun lẹẹkeji.”