Jide Alabi
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan niluu Ikọle-Ekiti, ti tu igbeyawo ogun ọdun ka laarin, Taiwo Olominu ati iyawo ẹ, Ajibikẹ. Ohun to si fa a ni pe ọrọ awọn tọkọ-tiyawo ọhun ko ye ara wọn mọ. Eyi ni adajọ fi ni ki kaluku maa ṣe tiẹ lọtọọtọ.
Ẹni ọdun mẹtalelaaadọta ni Olominu, alaye to si ṣe nile-ẹjọ ni pe ọmọ mẹrin ni obinrin naa bi foun, ṣugbọn ki i ṣe pe oun fẹ ẹ niṣu lọka gẹgẹ bii aṣa agbegbe awọn.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe oun ati obinrin ti oun kọ silẹ yii lawọn jọ n tọ awọn ọmọ naa, ṣugbọn oun gan-an loun maa n san owo ileewe wọn.
O ni Ajibikẹ ki i bọwọ foun, o lagidi, bẹẹ lawọn ẹbi oun paapaa ko jọ ọ loju rara. Baale ile yii ni ni nnkan bii ọdun mejila sẹyin loun ti kọkọ wọ ohinrin naa lọ sile-ẹjọ pe oun ko fẹ ẹ mọ, ṣugbọn nigba ti ẹbẹ pọ lọdọ awọn ẹbi lo jẹ ki oun foriji i nigba naa, ti awọn si n ṣe lọkọ-laya pada. Ṣugbọn ni bayii, ki ile-ẹjọ tu ajọṣepọ awọn ka, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.
Ọkunrin yii ti sọ pe oun ṣetan lati fi ile ti oun ati obinrin yii jọ kọ silẹ fun oun atawọn ọmọ to bi foun, lati gba alaafia laaye.
Bo tilẹ jẹ pe Ajibikẹ ko si nile-ẹjọ lọjọ naa, sibẹ, Aarẹ ile-ẹjọ ọhun, Arabinrin Yemisi Ojo, tu igbeyawo ọhun ka lori ẹsun agidi, ọrọ buruku ti ọkọ ẹ lo maa n sọ soun ati bi wọn ṣe maa n lu ara wọn lọpọ igba.
O ni niwọn igba tawọn mejeeji paapaa ko ti ṣeto igbeyawo kankan tẹlẹ, to jẹ pe niṣe ni wọn kan n bimọ funra wọn, ti wọn ko tun gbọ ara wọn ye, ki kaluku maa ba tiẹ lọ. Bẹẹ naa lo pa ọkunrin yii laṣẹ ko fi ile ti wọn jọ kọ silẹ, ko si maa sanwo ileewe awọn ọmọ ti obinrin naa bi fun un.