Adewale Adeoye
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii ni adajọ ile-ẹjọ kan ti wọn n pe ni ‘Area Court,’ niluu Jos, Onidaajọ Showami Bokkos, ti paṣẹ pe ki ọdọmokunrin kan, Matthew Danjuma, ẹni ọdun mẹrinlelogun, lọọ fẹwọn ọdun kan pẹlu iṣẹ aṣekara jura.
Ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin alapata yii ni pe o gun ọrẹ rẹ lọbẹ lasiko ti ede-aiyede kekere kan bẹ silẹ laarin awọn mejeeji.
Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Ibrahim Gokwat, to foju Matthew bale-ẹjọ sọ niwaju adajọ pe lojo kọkanlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni Matthew hu iwa ọdaju ọhun. O fi kun un pe Umar Muhammad ti Matthew Matthew gun lọbẹ lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan agbegbe ‘C Division’, kan leti.
Gokwat ni ṣe ni Matthew ṣi inu bi lakooko ti ede aiyede kan bẹ silẹ laarin awọn ọrẹ mejeeji naa ni Matthew fibinu fa ọbẹ yọ, nigba to kuku jẹ pe alapata ni tẹlẹ, ọbẹ ko figba kankan wọn lọwọ rẹ, eyi lo ṣe rọrun fun un lati gun ọrẹ rẹ yii lọbe laibikita rara sohun to le ṣẹlẹ si i.
Nigba ti agbefọba n ka ẹsun ti wọn fi kan ọmọkunrin naa, o ni ẹsun akọkọ ni pe o fọbẹ gun eeyan. Bakan naa ni wọn tun fẹsun igbiyanju lati paayan kan an.
Awọn ẹsun mejeeji yii ni wọn ni o lodi sofin ipinlẹ naa, ti ijiya nla si wa fẹnikẹni to ba hu iru iwa bẹẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Bokkso ni ki Matthew lọọ ṣẹwọn ọdun kan gbako, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọta Naira gẹgẹ bii owo itanran fohun to ṣe. Bakan naa ni adajọ paṣẹ pe ki Matthew tun san ẹgbẹrun lọna marundinlogoji Naira fun ẹni to gun lọbẹ, ko le jẹ ẹkọ nla fun un pe ki i sọhun to daa keeyan maa huwa bii ọdaran laarin ilu.
O ni idajọ naa yoo tun jẹ ẹkọ fawọn eeyan, paapaa ju lọ awọn ti wọn n ṣe bo ṣe wu wọn laarin ilu pe bọwọ ofin ba tẹ wọn, wọn yoo kabaamọ ohun ti wọn se.