Monisọla Saka
Abilekọ kan ati ọmọ ẹ obinrin ọmọ ọdun mẹjọ, ni wọn ti ṣe bẹẹ kagbako arun kogboogun HIV bayii, lẹyin ti ọrẹkunrin obinrin abilekọ naa, Jude Chinedu, ti inagijẹ ẹ n jẹ Ijiegbe, fipa ba ọmọdebinrin naa laṣepọ, nile wọn to wa nipinlẹ Delta.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ṣe sọ, agbegbe Alegbor, ijọba ibilẹ Uvwie nipinlẹ Delta, ni wọn ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Owuyẹ kan lagbegbe naa, ṣalaye pe afurasi ti fẹsẹ fẹ ẹ, ati pe esi ayẹwo ti wọn ṣe fobinrin ọhun atọmọ ẹ, fidi ẹ mulẹ pe awọn mejeeji ti ni kokoro aarun buruku yii ninu ẹjẹ wọn.
O ni, “Ọrẹkunrin ni afurasi jẹ si iya ọmọ naa, o si ti n gbe ni igbe ‘baba n yọ wa’ pẹlu wọn tipẹ diẹ. Nigba ti aṣiri tu pe o n fipa ba ọmọ kekere yẹn lajọṣepọ, lo ti sa kuro nile. Latigba naa, lawọn ọlọpaa si ti bẹrẹ si nii wa ọkunrin afurasi ọmọ ipinlẹ Anambra naa.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe, nigbakuugba ti iya ọmọbinrin to n ta ogi yii ba ti kiri lọ, ni Jude maa wẹ ọmọdebinrin ọhun, ti yoo si ba a lajọṣepọ. Lẹyin naa ni yoo ko ẹru si i lọkan, ti yoo kilọ fun un pe ọjọkọjọ to ba lanu sọ fẹnikẹni, pe ohun n ba a ṣe ohunkohun, loun maa pa a.
“Iya ọmọ yẹn lo kọkọ ṣakiyesi awọn nnkankan lara ẹ, ati bi ihuwasi ọmọ naa ṣe yi pada lojiji. Bẹẹ lo tun ri i pe omi to n ru buruku buruku kan n jade loju ara ọmọdebinrin naa, lẹyin ọpọlọpọ ifọrọwanilẹnuwo, to si tun pẹtu sọkan ọmọ naa, lo jẹwọ pe aimọye igba ni afurasi ti fipa ba oun lajọṣepọ, ti mama oun ba ti jade le. Nigba ti iya ọmọ naa si lọ sọ ọ kan afurasi loju, pe ṣe loootọ ni nnkan tọmọ yẹn sọ, lo sa kuro nile lọsan-an kan oru kan”.
Amọ ṣa o, ọkunrin ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Kelvin Ejumudo, ti lọọ fẹjọ ọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Ebrumede, lẹyin ti wọn ti ṣalaye bọrọ ṣe jẹ fun un.
Ikọ awọn agbofinro ati Ọgbẹni Ejumudo yii, ni wọn dijọ mu ọmọ naa lọ sile iwosan fun ayẹwo, nibẹ ni wọn ti ri i pe o ti lugbadi kokoro arun HIV. Lẹyin naa ni wọn mu iya ẹ lọ fun iru ayẹwo yii, bakan naa lo si ri foun naa.
Ọgbẹni Ejumudo ni, “Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ itọpinpin lori ibi tọkunrin naa wa, nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ ni wọn kọkọ fi n tọpasẹ rẹ bayii na. Diẹ bayii lo si ku ki ọwọ ba a l’Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun yii, amọ to yọ pọrọ wọnu igbo lọ”.
DSP Bright Edafe, ti i ṣe alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta o ti i sọ nnkankan lori iṣẹlẹ naa. Bẹẹ ni ko ti i fesi si atẹjiṣẹ ti wọn fi ṣọwọ si i lati ọjọ Aje ti iwadii ọrọ naa ti bẹrẹ.