Lẹyin ti wọn pa meji ninu wọn, awọn ajinigbe tu eeyan mẹrinlelaaadọrin silẹ lọjọ kan ṣoṣo

Monisọla Saka

Mẹrinlelaaadọrin, ninu eeyan tawọn agbebọn ji gbe labule Wanzamai, nijọba ibilẹ Tsafe, nipinlẹ Zamfara, ni wọn ti gba itusilẹ bayii.

Awọn eeyan ti wọn ji gbe lasiko ti wọn n wa igi idana ninu oko yii ni wọn gba idande lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lẹyin ti wọn ti san miliọnu mẹfa Naira owo itusilẹ.

Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni wọn ji awọn eeyan marundinlaaadọrun-un (85), gbe ninu oko, ti eeyan kan ninu wọn si mori bọ, ṣugbọn awọn agbofinro ni iye awọn ti wọn ji ko ko to iye ti wọn n sọ, wọn ni eeyan mẹsan-an pere lawọn agbebọn ji gbe sa lọ.

Amọ ṣa o, Abubakar Na’Allah, ti i ṣe ọkan lara awọn olori ilu naa ni irọ ni iye awọn eeyan tawọn ọlọpaa sọ, o lawọn agbebọn yii ti kan sawọn, ati pe miliọnu meji din lọọọdunrun Naira (1.7 million), ni wọn n beere fun lọwọ awọn ti wọn ji gbe. O ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira, ni wọn pe owo itusilẹ ori kọọkan awọn eeyan to wa lakata wọn ọhun.

Nigba ti eeyan kan lati abule ti wọn ti ji awọn eeyan ko yii n ṣalaye fawọn oniroyin, o lawọn ajinigbe ọhun ti tu awọn mẹrinlelaaadọrin silẹ ninu awọn marundinlaaadọrun ti wọn ji gbe lọ.

O ni meji ninu awọn eeyan naa ni wọn ti pa, eyi lo si mu kawọn to ṣẹku si akata awọn ẹni ibi yii ku mẹsan-an. Wọn lawọn eeyan ti wọn ti ri idande gba yii wa nile iwosan aladaani kan nipinlẹ naa, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

 

Leave a Reply