Alele-Williams, obinrin akọkọ to jẹ ọga agba fasiti ni Naijiria, jade laye

Faith Adebọla

 Abilekọ Grace Alele-Williams, obinrin to fitan balẹ lọdun 1985 gẹgẹ bii ọga agba fasiti ni Naijiria ti doloogbe.

Mama arugbo naa jade laye nile rẹ to wa l’Ekoo,  lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii, lẹni ọdun mọkandinlaaadọrun (89) ọdun.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Disẹmba, ọdun 2021, to kọja yii, ni mama naa ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun kọkandinlaaadọrun rẹ loke eepẹ, Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari, atawọn eeyan jannkan jannkan lẹka eto ẹkọ ba mama naa yọ, wọn ki i ku oriire, wọn si ṣe sadankata fun un fun ipa ribiribi to ko lasiko to fi wa nipo ọga agba Fasiti Benin, ti ipinlẹ Edo.

Yatọ si pe oun lẹni akọkọ lobinrin ti yoo depo naa nilẹ wa, Alele-Williams tun ni obinrin akọkọ ti yoo gba oye ọmọwe (Doctorate) ninu imọ iṣiro (Mathematics), ọdun 1963 lo gboye yii, iru nnkan bẹẹ si ṣọwọn gidi lawọn ọdun yẹn.

Lasiko rẹ gẹgẹ bii ọga agba Fasiti Benin, Alele-Williams mu adinku gidi ba iwa ṣiṣẹgbẹ okunkun, o si fakọ yọ ninu akoso fasiti naa, eyi to sọ ọ di ilumọ-ọn-ka.

Titi dasiko yii, a o ti i mọ pato ohun to ṣokunfa iku Alele-Williams, bẹẹ si lawọn mọlẹbi rẹ ko ti i kede bi ayẹyẹ eto isinku rẹ yoo ti lọ si.

Leave a Reply