Alẹsanmi lu ẹgbọn rẹ pa ni Kiribo, ọmọ-odo lo la mọ ọn lori

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Akurẹ ti ni ki wọn si lọọ fi olujẹjọ kan, Alẹsanmi Iwalẹfun, pamọ sọgba ẹwọn, lori ẹsun siṣeku pa ẹgbọn rẹ.

Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni wọn fẹsun kan pe o la ọmọ-odo mọ ẹnikan ti wọn n pe ni Orimisan lori lasiko ti wọn n ja, eyi ti wọn lo ṣokunfa iku airotẹlẹ fun un.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye laduugbo Madagbawu, niluu Kiribo, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, lọjọ kẹrinlelogun, osu kin-in-ni, ọdun ta a wa yii.

Ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun ni wọn lo lodi si abala okoolelọọọdunrun din mẹrin (316) ati okoolelọọdunrun din eyọ kan (319) ninu iwe ofin tipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Agbefọba, Taiwo Oniyẹrẹ, rọ ile-ẹjọ lati fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi digba ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n ń gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Ó. L. Abu gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ni ki wọn ṣi lọọ fi ọkunrin naa pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ kẹjọ, osu kẹta, ọdun 2021.

 

Leave a Reply