Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni Eleweeran, l’Abẹokuta, lawọn ọlọpaa ti ṣafihan ọkunrin kan, Aluchi Emmanuel, pẹlu ẹni keji rẹ, Mark Okoro.
Ẹnikan ti oun ati Aluchi jọ n gbele ni Lusada, l’Ado-Odo Ọta, tiyẹn n fi ẹrọ POS ṣiṣẹ ni afurasi yii ran awọn ole si, bawọn iyẹn ṣe fibọn gba miliọnu mẹta ataabọ naira (3.5m) lọwọ ọkunrin to n fi POS ṣiṣẹ aje naa niyẹn.
Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ f’AKEDE AGBAYE, Aluchi sọ pe owo wa lọwọ araale oun naa daadaa, nitori oun maa n ri i bawọn eeyan ṣe maa n waa gbowo nla lọwọ ẹ, ti wọn ki i lọ si banki mọ bo ti wu kowo ọhun pọ to.
O ni o wu oun naa koun lowo lọwọ bẹẹ, ko si sọna toun yoo gbe e gba, ohun to jẹ koun pe Mark, ọrẹ oun ati ẹni kẹta awọn to ti sa lọ bayii niyẹn. O loun sọ fun wọn pe ki wọn waa ja araale oun yii lole, bi wọn ba ti rowo gba lọwọ ẹ, awọn yoo jọ pin in.
Eyi ni Mark ati ẹni keji ẹ ṣe lọ sile awọn Aluchi lọsẹ mẹta sẹyin, wọn yọ ibọn si ọkunrin naa, wọn si gba miliọnu mẹta aabọ lọwọ ẹ, bẹẹ ni wọn ko awọn ẹrọ POS tiyẹn fi n ṣiṣẹ lọ.
Wọn ti ṣiṣẹ ọhun tan nirọrun gẹgẹ bi Aluchi ṣe wi, ko sẹni to fura si i. O loun gan-an loun tiẹ fi ọkada oun gbe ọkunrin ti wọn ja lole naa lọ sibi ti wọn ti ri awọn ẹrọ POS rẹ, ninu igbo.
O loun sọ fun un pe oun yoo ran an lọwọ lati ri gbogbo ohun ti wọn gba lọwọ ẹ yẹn pada, eyi ni ko jẹ ki wọn fura soun pe oun gan-an ni baba isalẹ awọn meji to waa jale naa.
Ṣugbọn nigba ti aṣiri yoo tu, oju opo Fesibuuku ti Aluchi n lo, lo ko ba a. Fọto Mark, ẹni to gbe ibọn si ọkunrin naa lori nigba ti wọn n gbowo lọwọ ẹ niyẹn ri loju opo Aluchi.
Bo ṣe ri i lo da a mọ pe ọkan ninu awọn to ja oun lole ree, bo ṣe lọọ fi akiyesi to ṣe naa to awọn ọlọpaa leti niyẹn.
Awọn ọlọpaa waa gbe Aluchi nile, wọn si fọrọ wa a lẹnu wo titi to fi jẹwọ pe oun loun ran Mark Okoro ati ẹni keji ẹ wa lati ja araale oun lole.
Ẹni kẹta wọn naa lawọn ọlọpaa ṣi n wa bayii, wọn ti Aluchi ati Mark mọ gbaga lọdọ awọn SARS, wọn yoo si de kootu laipẹ.