Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Araba Awo ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti ke si ijọba apapọ lati fi ọwọ to nitumọ mu ẹsin ibilẹ, ki ohun kan ṣoṣo to jẹ ami idanimọ iran Yoruba ma baa parun.
Lasiko ti wọn n ṣi tẹmpili nla onimiliọnu lọna ogun Naira, eleyii ti agbarijọpọ awọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, labẹẹ Ile Ijuba Ì̀din Ilẹkẹ kọ si ilu Oṣogbo, ni Ẹlẹbuibọn ti sọrọ naa.
Araba Awo ṣalaye pe ti ijọba apapọ orileede yii ba le mojuto ọrọ ẹsin ibilẹ daadaa, ẹgbẹẹlẹgbẹ biliọnu Naira ni yoo maa wọle labẹnu lati ẹka naa.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘O tọ ki a mọ pe ẹsin ibilẹ n ko ipa nla ninu aṣa ati awujọ ilẹ Adulawọ lonii. Ibanujẹ nla lo jẹ pe ẹsin naa ko fi taratara jẹ itẹwọgba latari pe awọn eeyan ko ni ẹkọ ijinlẹ lori ohun ti ẹsin yii jẹ mọ.
‘Tijọba apapọ ba le ṣamojuto ẹka naa bi wọn ṣe n ṣe ni ẹka to ku, wọn yoo ri i pe anfaani nla ni Eledumare fun wa lorileede yii. ‘Ile ti a n ṣi lonii yii duro fun gbigbe ẹsin ati aṣa larugẹ. Ile ijuba yii n tọka si bi gbogbo wa ṣe nigbagbọ ninu awọn oriṣa wa ati bi a ko ṣe foju imẹẹri wo awọn aláṣekù wa’
Ile Ijuba naa, eyi ti wọn pe ni akọkọ iru rẹ lorileede yii, ni Baba Ẹlẹbuibọn sọ pe yatọ si pe yoo wa fun awọn olujọsin, yoo tun jẹ ojuko kan fun awọn ti wọn ba nifẹẹ lati kọ nipa ẹsin ibilẹ tabi lati ni oye kikun si i nipa rẹ.
Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ Oniṣẹṣe, iyẹn, Traditional Religion Worshippers Association, Oloye Ifagbenuṣọla Atanda, ṣalaye pe, pẹlu Ile ijuba naa, yoo ṣoro fun awọn ẹlẹsin atọhunrinwa lati ko awọn ọmọ Ifa lọ.
Oloye Atanda sọ siwaju pe yoo jẹ ibi ijọsin ti gbogbo awọn ẹlẹsin ibilẹ yoo ti maa pade loorekoore lati sin Olodumare.
Ṣaaju ni ọkan lara awọn ọmọ igbimọ ti wọn kọ ile naa, Ogundeji Ẹlẹbuibọn, sọ pe kaakiri agbaye ni awọn ọmọ ẹgbẹ oniṣẹṣe ti da owo jọ lati fi kọ ile Ijuba ọhun.
O ni laarin oṣu mejilelogun lawọn fi kọ ile ti owo rẹ jẹ miliọnu lọna igba Naira ọhun, nipasẹ oninu-didun-ọlọrẹ lawọn si fi ṣaṣeyọri rẹ.